Hajiya Binta Balarabe Kubaus: Obìnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he ní Kaduna lẹ́yìn tó lu jìbìtì ₦5.5m

Oríṣun àwòrán, other
Obìnrin kan ti ri ẹwọn ọdun mẹwàá he lẹyìn tó jẹbi ẹsun lílu jibiti ni Kaduna.
Adájọ M.T.M Aliyu lo ṣe idajọ náà fún un lẹyìn tí àjọ EFCC fẹsun lílu jibiti owo ti iye rẹ le ni mílíọ̀nù marun un kan an.
Ìròyìn ní inú oṣù Kẹjọ, ọdún 2020 ni afurasi naa hu ìwà òdaran ọhun.
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Gbajabiamila pé: Kò yẹ kí ẹni tí kò kà ju WAEC bíi Buhari jẹ Ààrẹ Naijiria mọ́
- Ilé ẹjọ́ ní kí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò san 4.5m fún alájọgbélé wọ́n tí ariwo 'toilet' wọn kò jẹ́ kó rí oorun sùn
- Fayoṣe ló ń dá PDP Ekiti rú, inú iyàrá kan ni àwọn igún OPA ti kọ orúkọ àwọn aṣojú- Senato Olujinmi
- Lóòtọ́ ni àrùn Lassa ti wọ ìpìnlẹ́ Oyo, àmọ́ ẹ má mikàn- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- DSS, ẹ jẹ́ kí Kanu pààrọ̀ aṣọ tó ń wọ̀ wá sílé ẹjọ́ mi bí bẹ́ẹ̀ kọ́.......- Adajọ Binta Nyako
- Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Abia àti Imo wọ àṣo àsíí Biafra bí o ṣe jáde lórí ayélujára?
Wọn ní ọ parọ fún okunrin kan, Yahaya Mohammed Idris, pe òun yóò ta ilẹ fún lọna ati gba owo lọwọ rẹ.
Wọn ní ohun tí Hajiya Binta Balarabe Kubaus, obinrin naa ṣe lodi si òfin ìwà ọdaran ipinlẹ Kaduna, eyiti wọn gbe kalẹ lọdun 2017.
Ẹwẹ, afurasi náà sọ níwájú adájọ pe lootọ ni òun ṣe sí òfin náà, ṣugbọn ki wọn fi ojú aanu wo oun.
Agbejoro Hajia Binta, Sule Shuahibu bẹbẹ lẹyin ti onibara rẹ gab pe oun jẹbi ẹsun naa.
Bó tilẹ jẹ pé afurasi naa ti sọ pé òun yóò dá owó náà padà fun okunrin to lu ni jibiti.
Adájọ ni ko lọ fi ẹwọn ọdun mẹ́wàá jura, tabi ko san ẹgbẹrun lọnà ìgbà náírà owo itanran le\yin to ti setan sisan owo naa pada.
Ṣaaju ni ẹni tí Hajiya Binta Balarabe Kubaus, obinrin naa lu ni Jibiti ti kọkọ kọwe mọ ọ ni ọọfisi EFCC pé ayédèrú iwe ilẹ lọ fún òun kí ọrọ náà tó dé iwájú Adájọ.
Orọ ilẹ ni wọn fi ṣe owo naa ni Kaduna ni eyi ti iwe ẹri wọn yatọ si ara wọn.















