Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá ba akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìyàwó, ikú dé!

Oríṣun àwòrán, @Francis Agube
Ọlọpaa kan ti dero atimọle lẹyin ti ọta lati inu ibọn rẹ ṣeeṣi pa akẹgbẹ rẹ kan ni ipinlẹ Cross Rivers.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye fun BBC pe aipẹ yii ni oloogbe naa, Sergeant Francis Agube, ṣẹṣẹ gbe iyawo.
Iṣẹlẹ naa waye ni opopoa Effigy lasiko ti awọn agbofinro ọhun n ṣiṣẹ igboro.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Irene Ugbo sọ pe oṣu Kọkanla, ọdun to kọja ni oloogbe na ṣe igbeyawo, koda, aya rẹ ọhun ti fẹraku.
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún DSS láti san bílíọnù kan Naira fún Nnamdi Kanu
- Wo bí ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n jígbé ni Ibadan sí Eko ṣe gba òmìnira lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá
- Oluwo: Ààrẹ Buhari, ẹ dájọ́ ikú fún gbogbo ẹni tó ń gbé òògùn olóró, agbésùnmọ́mi àti afinisoogun owo
- Irọ́ ni Tinubu ń pa o, PVC kìí parí iṣẹ́ – INEC
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye:
Oṣiṣẹ ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran, SCID, lawọn agbofinro mejeeji ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ibọn naa ba oloogbe ọhun ni ọrun, o si ba gbogbon oju rẹ jẹ yanayana.
O ni "wọn n wa ọkọ bọ lagbegbe Effigy, nigba ti wọn de iwaju agọ wọn ni Uji bẹrẹ si n ṣe ayẹwo ibọn rẹ."
"Bo ṣe n yẹ ibọn naa wo lọwọ ni ọta dede fo jade lati ninu rẹ to si ba Agube to joko siwaju rẹ."
Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Ọọfisi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti sọ pe awọn ti gbe oku oloogbe naa lọ sile igbokupamọsi.
- Super Eagles Nàìjíríà gún Guinea Bissau ní kẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú 2-0
- Ilé ẹjọ́ gbà béèlì ìgba mílíọ̀nù Naira(N200m) lórí ẹsùn tí EFCC fi kàn Mompha
- Ǹjẹ́ obìnrin leè di "virgin" padà bí kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbá pípẹ́? - Onímọ̀ nípa ìbálòpọ̀ bá BBC sọ̀rọ̀
- Pẹ̀lú bí Dayo Kujore ṣe fi ayé rẹ̀ sin Nàìjíríà tó, kò sí ẹnìkan tó bá wa kẹ́dùn lẹ́yìn ikú rẹ̀- Ayinke Kujore
- Ẹ yìnbọn pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n- Mínístà Aregbesola
Wọn ni awọn tun ti bẹrẹ iwadii, ati pe ọlọpaa to ṣeṣi yinbọn pa akẹgbẹ rẹ naa ti wa ninu ahamọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa pari ọrọ rẹ pe "A ko ni sin oku oloogbe titi ti a oo fi pari iwadii wa… ohun ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ, amọ a oo ṣe iwadii to tọ lori rẹ."















