Davido and Dele Adeleke: Njẹ́ ọ̀rọ̀ ipò gómínà Osun ní 2022 kò fẹ́ ẹ̀ da ẹbí Adeleke rú báyìí?

Ọmọ ẹbi kan naa ni Dele ati Demola Adeleke to jọ fẹ ẹ dije fun ipo gomina Osun ni 2022

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ẹbi kan naa ni Dele ati Demola Adeleke to jọ fẹ ẹ dije fun ipo gomina Osun ni 2022
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Njẹ ọrọ taa ni yoo dije fun ipo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2022 ko ti fẹ ẹ ma a da ẹbi Adeleke ru?

Eyi ko ṣẹyin bi gbajugbaja olorin, David Adeleke ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido, ati ibatan rẹ kan, Dele Adeleke ṣe n sọ oko eebu ati ọrọ buruku si ara wọn lori ayelujara.

Ọjọ Iṣẹgun ni davido kọkọ kọ awọn ọrọ kobakungbe si ori ayelujara Twitter rẹ nipa Dele, nibi to ti pe e ni ayederu eeyan ati ọbayejẹ.

Davido sọ pe akurẹtẹ eniyan ni Dele, tako bi onitọhun ṣe ṣapejuwe ara rẹ ni ọmọwe, onimọ ati ẹni to ni oye.

Ṣaaju ni Dele kọ si ori ayelujara pe jijẹ oloye ati ẹni to ni imọ ko ṣe e dọgbọn si tabi fun eeyan lọfẹ-lofo.

O ni suuru, ifọkansin ati ikoraẹni ni ijanu ni eeyan nilo lati ni iru nkan bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

"O ku sọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati da iru ẹni bẹẹ mọ, ki wọn si sẹ atilẹyin fun-un".

O sọ eyi lẹyin to gba fọọmu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP, lati dije fun ipo gomina ipinlẹ Osun lọdun yii.

Ẹsun ti Davido fi kan Dele ni pe ko bojumu bi oun naa ṣe fẹ ẹ du ipo gomina, nigba to mọ pe ibatan awọn mejeeji, to jẹ aburo fun awọn baba wọn, Sẹnetọ Ademola Adeleke naa fẹ ẹ dije.

Ademola Adeleke ti kọkọ dije fun ipo naa lọdun 2018, ṣugbọn gomina Gboyega Oyetola gba a mọ lọwọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Ọgbẹni Dele ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels lọjọ diẹ sẹyin, lo ti sọ pe oun koju osunwọn ju "uncle" oun lọ.

Nigba to n fesi si awọn ọrọ buruku ti Davido kọ nipa rẹ, Dele sọ pe awọn ololufẹ gbajugbaja akọrin naa ti n dunkooko mọ oun, lẹyin ọrọ to kọ nipa oun.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

O ni "mo faramọ ipinnu rẹ lati ṣatilẹyin fun Uncle Demola. Amọ mo fẹ ki o mọ pe onikaluku wa le yan ipa to wu u, lai jẹ ko da ẹbi wa ru.

"Nkan to dara lo tọ si awọn eniyan ipinlẹ Osun, mo si mọ pe wọn o gbe iṣẹ fun ẹni ti wọn ba ro pe o le ṣe daadaa.

"Ni temi, bi mo ṣe n ni suuru lati atẹyinwa naa ni ma a tẹsiwaju lati ma a ṣe."

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ṣugbọn awọn nkan to kọ yii tun bọ mu inu bi Davido, eyi to mu ko tun pada sọ awọn ọrọ ibinu si ibatan rẹ ọhun, paapaa bo ṣe jẹ pe iya oun lo tọ ọ dagba, ati pe baba oun lo fun-un ni ile to n gbe lọfẹ.

Ọrọ naa n fa ariyanjiyan lori ayelujara lọwọlọwọ.

Àkọlé fídíò, Eba

Bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe lootọ ni ko tọ fun Dele lati gbe igba ibo gomina ipinlẹ Osun, ni awọn kan n sọ pe ko si nkan to buru nibẹ.

Awọn miran ti ẹ n gba wọn ni imran pe ki wọn o deẹkun lati ma a fi mọlẹbi wọn ṣẹṣin lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Taa ni Dele Adeleke?

Bamidele Adeleke ni orukọ rẹ ni ẹkunrẹrẹ.

Lọdun 2018 ti Ademola Adeleke dije dupo gomina ipinlẹ Osun, ipa kekere kọ ni Dele ko. Nitori pe oun lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ ati aṣoju oludije naa nibi ọpọlọpọ nkan.

Bakan naa lo ja fitafita nile ẹjọ lẹyin ti ajọ INEC kede pe Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi