Osun Election Results 2018: Dele Adeleke: Ǹkan tó tọ́ sí Ọṣun kọ́ ni INEC fún un
Àriwisi àwọn ará ìlú ṣe ọtọtọ lórí èsì ìdìbò Osun lẹyin ti Ajo INEC kede Gboyega Oyetola gẹgẹ bi gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Ọsun.
Ajọ eleto idibo INEC ti kede Gboyega Oyetola labẹ ẹgbẹ oselu APC gẹgẹ bi gomina ti wọn dibo yan ni ipinlẹ Ọsun fun ọdun mẹrin to m bọ.
Dele Adeleke, Aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ohun ibanujẹ lo jẹ fun oun nitori pe ifẹ awọn ara Ọṣun kò wa si imusẹ lasiko idibo naa.
Adeleke fikun un pe Ajọ eleto idibo INEC to yẹ ko duro si ipo otitọ kọ lati se isẹ wọn bii isẹ.
Ọ wa parọwa si gbogbo awọn ara Ọsun lati fi ọkan balẹ ati pe ọdun kan pere ni iya yii yoo mọ fun awọn ara Ọsun.