Osun rerun election: ''Olè jíjà tó tìí lágbara ni àtúndì ìbò tòní-PDP

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Ọṣun, Sọji Adagunodo, ti ṣàpéjúwe àtúndì ìbò gómìnà tó wáyé l'Ọṣun gẹ́gẹ́ bi àjálù nla fún ètò ìṣèjọba àwa-ara-wa àti olè jíjà tó tìí lágbara jù ní ẹ̀kun Ìwọ̀ oòrùn Gúùsù Nàìjíríà.

Adagunodo fi ẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, pé wọ́n ṣe màgò-mágó nínú àtúndì ìbò tó wáyé ọ̀hún.
Ó sọ pé ''àwọn jàndùkú ẹgbẹ́ APC kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ìjọba ìbílẹ̀ Ọrọlu, Ifẹ North ati Ifẹ South, dìbò.
Lára àwọn ẹ̀sùn tó tọ̀ka sí ni:
- Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ PDP ní Ọrọlu, Ifẹ North ati Ifẹ South, ni àwọn jàndùkú kọlù pẹ̀lú ìbọn àti àdá níṣojú àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò, tí wọ́n sì kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ kankan.
- Ogúnlọ́gọ̀ àwọn tó ní káàdì ìdìbò ní ànfàánì láti dìbò ní ibúdò tí kìí ṣe ti wọn ní ìjọba ìbílẹ̀ Oṣogbo àti Ife South.
- Wọ́n kò jẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn àti àti àwọn ònwòye ìdìbò wọ àwọn ibùdó ìdìbò kan.
- Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn yóò fi ri àáyè dé àwọn ibùdó ìdìbò nàá ní nkan bi agogo mọ́kànlá òwúrọ̀, àwọn aṣojú APC tó n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ INEC ti kó ìbò APC sínú àwọn àpótí ìbò.
- Wọ́n fi àáké ṣá asọjú ẹgbẹ́ PDP kan ní agbègbè Ọlọdẹ
Àwọn èékàn nínú ẹgbẹ́ PDP bí Sẹ́nétọ̀ Ben Murray-Bruce àti alukoro ẹgbẹ́ PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan nàá ti bú ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúndì ìbò nàá.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Adagunodo sọ pé ó dun òun bí àtúndì ìbò tí INEC gbékalẹ̀ ní àwọn ibùdó ìdìbò méje ní màgò-mágó nínú.
Nítorí èyí ló ṣe sọ pé òun kò ní gba èsì 'ìdìbò awúrúju nàá, tó sì gba àwọn aláṣẹ INEC ní ìmọ̀ràn láti dáwọ́ kíka ìbò nàá dúró.









