Yollywood: Shina Peller, Desmond Eliot, Akin Alabi, Rotimi Makinde, Adebo Ogundoyin gbégbá àpótí òṣèlú

Yollywood

Oríṣun àwòrán, others

Ipo asoju araalu nile asofin yala nijọba ipinlẹ tabi ni ile asofin agba Naijiria jẹ eleyi ti o wu ọpọ eeyan ni Naijiria.

Yatọ si pe yoo tan irawọ eeyan sita faraye gbọ, ipo naa tun jẹ eleyi ti owo wa nibẹ nitori owo gọbọi tawọn asofin Naijiria n gba lowo osu ati ajẹmọnu mii.

Ba se n ri awọn ọmọwe to n dije du ipo yi laa n ri awọn onisowo koda ko yọ awọn gbajumọ ati sere tiata mi lẹsẹ ni lẹ.

Wọn yi ni diẹ lara awọn gbajumọ to ti di asofin ni Naijiria taa ri ka seti igbọ yin.

1. Desmond Elliot:

Oluwashola Desmond Elliot jẹ gbajumọosere tiata Nollywood ko to sọ pe oun fẹ dan agbami oselu wo.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Lati igba to si ti darapọ mọ oselu, ko fẹ ẹ si oloselu irọ rẹ ti awọn eeyan foju si lara bi ti Desmond Elliot.

Asoju ẹkun Surulere nile asofin ipinlẹ Eko yi dabi ẹni pe o fẹnukọ paapa lọdọ awọn ọdọ lori ọrọ to sọ nipa ENDSARS ati awọn to n lo ẹrọ ayelujara.

Ojumọ kn eebu kan ni wọn a maa fi ransẹ si Desmond Elliot koda lori ọrọ ti ko kan Elliot, wọn a tun sọ pe ẹbi rẹ ni.

2. Shina Peller:

Ọmọ baba ọlọwọ idan, Shina Peller n soju ẹkun Iseyin/Itesiwaju/Iwajowa/Kajola nile asojusofin apapọ Naijiria.

Saaju ko to darapọ mọ oselu, Peller jẹ gabjugbaja onisowo to si ni awọn ileesẹ to fi mọ ile ariya Quilox tawọn gbajumọ a ti maa se faaji titi di isin.

Lẹnu igba to ti di asoju yi, Shina Peller ati awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko ti figagbaga lori pe o ko awọn janduku lọ sigun ba awọn ọlọpaa lagọ wọn.

Shina Pellers

Oríṣun àwòrán, @Shina Pellers Instagram

Ọrọ naa nise pẹlu isẹlẹ kan to waye nigba tawn to wa si ile ariya rẹ Quilox fi ọkọ di oju ọna ti wọn si da sunkẹrẹ fakẹrẹ silẹ loju popo.

Awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn sọ fun Peller pe ki wn seto lilọ bibọ ọkọ loju ọna fẹsun kan Peller pe o ko awọn janduku wa koju ọlọpaa lẹyin ti wọn ko awọn ọkọ kan to di ọna wa si agọ wọn.

Akin Alabi

Oríṣun àwòrán, @Akin Alabi

3. Akin Alabi

Olukọni ati ọlọrọ iyanju ni Oloye Akin Alabi jẹ ti kii si se aimọ fun ọpọ eeyan lori ayelujara.

Ohun ni oludasilẹ ileesẹ to n seto tẹtẹ tita nii,NairaBET to si pẹka kaakiri Naijiria.

Lọjọ Karun un, osu Kẹwaa, ọdun 2018 ni Alabi jaweolubori gẹgẹ bi asoju ẹgbẹ APC fun ipo asofin nile asojusoofin ti yoo soju ẹkun idibo Egbeda/Ona Ara ni ipinlẹ Oyo.

Yatọ si isẹ oselu, o tun ni ajọ ẹlẹyinju aanu tiẹ.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

4. Rotimi Makinde

Ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni adumaadan osere tiata Yoruba tẹlẹ yi to ti wa di oloselu.

Nigba to fi jẹ asoju lati ipinlẹ Osun, Makinde ni igbakeji alaga igbimọ ile asojusofin lori ẹtọmọniyan nile asofin ipele Keje.

Rotimi Makinde

Oríṣun àwòrán, @RotimiMakinde

Lọwọ bayi a gbọ pe o wa lara awọn to n polongo erongba Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fun ipo aarẹ Naijiria eleyi taa mọ si SWAGA.

Laipẹ yi lo sọrọ nipa wahala to de ba Baba Ijesha lori ẹsun asemase pẹlu ọmọde ti wọn fi kan an.

Makinde parọwa si awọn eeyan nigba naa lati jẹ ki ile ẹjọ dajọ lori Baba Ijesha dipo ki wọn maa da lẹbi lọwọ ara wọn.

Makinde lo ni ileesẹ redio Oodua FM to wa ni Ile Ife ni ipinlẹ Osun.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

5. Adebo Ogundoyin

Adebo Ogundoyin ni olori ile asofin to kere julọ lọjọ ori ni Naijiria.

Saaju ko to di asofin, Debo ni ajọsepọ pẹlu akọrin takasufe nii, Davido ti wọn si jijọ n sakoso ileesẹ rẹkọdi orin DREMO titi di ọdun 2018 to wọle sipo asofin ni Oyo.

Abẹ oselu PDP ni wọn ti dibo gbe wọle sipo to si ti wa fẹsẹ rinlẹ lagbo oselu ipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Eba

Lai pẹ yi lo se igbeyawo ti ilu gbọ ti gbogbo aye si mọ.

Fasiti Babcock lo ti kawe gboye to si jẹ asoju ẹkun idibo Ibarapa East.

Ile ni Debo ti ba oselu nitori baba rẹ oloye Adeseun Ogundoyin jẹ gbajugbaja oloselu .

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Nigba aye rẹ, bi wọn ba ti n darukọ Alhaji Arisekola Alao, Oloye Akanni Aluko, wọn a si maa darukọ tiẹ naa gẹgẹ bi gbajumọ asiko rẹ.

Ọdun 1991 ni Oloye Adeseun fayesilẹ.

Ọdun mẹrin pere ni Adebo wa nigba naa.