Student beats teacher: Akẹ́kọ̀ọ́ àti ìyá rẹ̀ kó àwọn jàndùkú lọ lu olùkọ̀ọ́ rẹ̀ l'Ogun

Ogun

Oríṣun àwòrán, Others

Wọn ti fẹsun kan akẹkọọ ile ẹkọ girama kan, Joshua Joseph, pe oun ati iya rẹ ko awọn janduku sọdi lati da bantẹ iya fun olukọ rẹ.

Akẹẹkọ naa jẹ ọmọ ile ẹkọ Toyon High School, to wa ni Ere, ni Ado-Odo, ni ipinlẹ Ogun.

Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn ni ki awọn obi tọwọ bọwe adehun pe awọn ọmọ wọn yoo dẹkun iwa ipa si awọn olukọ wọn ni ipinlẹ naa.

Iroyin ni wahala naa bẹrẹ lẹyin ti olukọ ti ọrọ ọhun ka, Kabir Azeez ni ki akẹkọọ naa pada sile lati lọ gẹ irun ori rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn olukọ mii, Abel Thomas and Adegun Adekunle tun farapa yanayana lasiko ikọlu ọhun.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Bẹẹni wọn tun ba ọkọ okunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Jolayemi Jeromu jẹ nibi ikọlu naa.

Ọga agba kan nile ẹkọ naa ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn agbofinro ti ba akẹkọọ naa, iya rẹ, to fi mọ ọkan lara awọn janduku ti wọn ko sọdi lati wa da seria fun olukọ ti a n wi yii.

Oga agba naa ni pe: "Lọjọ Aje, a ni ki akẹkọọ wa lọ ge irun ori rẹ nitori irun to ṣe ko ba ilana ile ẹkọ wa mu, ṣugbọn o tun gbe irun kan naa wa sile ẹkọ lana."

"Mo gba apo iwe rẹ, mo si ni ko lọ ge irun ọhun ko to pada wa lati gba baagi rẹ to ba ti ge irun naa tan."

"Nigba ti yoo fi pada wa, oun ati obinrin meji ati okunrin meji lo pada wa, ti awọn eeyan naa si n bi wa eredi ti a fi ni ko lọ ge irun rẹ."

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Oṣiṣẹ ile ẹkọ naa pari ọrọ rẹ pe "Mo gbe baagi rẹ fun wọn, mo si ni ki wọn lọ maa kọ lẹkọ ọ nile wọn… lẹyin naa ni wọn jade ti wọn si bẹrẹ si n pariwo, ti wọn tun n na awọn olukọ, koda, wọn fọ gilaasi ọkọto wa ninu ọgba wa."

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke