Marina Bridge repairs: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ṣíṣe àtúnṣe lórí rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta

Eko

Oríṣun àwòrán, Others

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde wí pé afárá Marina ni yóò wà ní títì pa fún ìgbà díẹ̀ kí ìjọba àpapọ̀ le ṣe àtúnṣe lórí ọ̀nà náà.

Èyí ní o ti bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kìíní títí di ọjọ́ kejì, oṣù kẹrin, ọdún 2022.

Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko, Dókítà Frederic Oladeinde ní ipele méjì ni àtúnṣe náà yóò gbà wáyé.

Ó ní ipele àkọ́kọ́ yóò wáyé láàárín ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kìíní sí ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹta níbi tí àtúnṣe yóò ti máa wáyé lórí apá kan afárá náà tó n jáde láti Apapa.

Bákan náà ló ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹ́ta sí ọjọ́ kejì, oṣù kẹrin ni àtúnṣe yóò wáyé lórí apá kan afárá ọ̀hún tó ń wọ Apapa.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Oladeinde ṣàlàyé pé àwọn ọkọ̀ tó ń jáde láti Apapa ni wọn yóò máa darí gba RRS àti afárá Total, tí àwọn kéékèèké yóò máa gba Beach Marine gba ti ilé epo Mobil láti já sí afárá Ìjọrá tàbí kí wọ́n gba Leventis bọ́ sí Naval Dockyard láti bọ́ sí abẹ́ Afárá Total.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Ó fi kun un pé nígbà tí iṣẹ́ bá bẹ̀rẹ̀ ní apá keji tó wọ Apapa, wọn yóò máa darí ọkọ̀ láti ri dájú pé kò sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ láàárín Afárá Total sí RRS.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Nígbà tó ń sọ àrídájú rẹ̀ pé iṣẹ́ ti ń lọ lọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀nà wọ̀nyìí, Oladeinde ní àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA yóò wà ní sẹpẹ́ láti ri dájú pé lílọ̀ bíbọ̀ ọkọ̀ jẹ́ ìrọ̀rùn.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe jẹ́jẹ́ lójú pópó nítorí kí lílọ̀ bíbọ̀ ọkọ̀ le rọrùn ní àtúnṣe náà wà fún.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?