Kidnapping on Lagos-Ibadan Expressway: Ọ̀gá Ọlọ́pàá Oyo tí gbé ikọ̀ agbógun tìjínigbé kalẹ̀ sí òpópónà Lagos-Ibadan Expressway

Oríṣun àwòrán, oyoaffairs.net
Kọmiṣọna ọlọpaa, l'Ọyọ Ngozi Ọnadẹkọ ni ikọ ọlọpaa agbogun tijinigbe Anti-kidnapping Squad yoo bẹrẹ iṣẹ lopopona marosẹ Eko sibadan
Ọga ọlọpaa Ọnadẹkọ ṣalaye lasiko abẹwo rẹ si ẹkun ipinlẹ lopopona marosẹ naa pe ohun ti wọn gbero ni lati rii pe awọn ọlọpaa n fioju han daadaa ni opopona naa lati lee wa ọwọ iwa ijinigbe to ti fẹ di tọrọ fọnkale lopopona marosẹ Eko si Ibadan bayii.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ni ko si idi fun awọn arinrinajo lo n gba opopona naa lati paya nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo bẹrẹ si nii gbe igbesẹ to ba yẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia loju opopona naa.
O ni yatọ si ikọ agbogun tijinigbe Anti-kidnapping Squad, awọn ikọ kogberegbe Swift Response Squad ati Skynet naa yoo kun wọn.
Bakan naa lo fi kun un pe awọn ikọ ọlọpaa latawọn ipinlẹ miran ti opopona naa gba kọja yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ikọ naa lati da awọn ajinigbe lẹkun iṣẹ buruku wọn lopopona ọhun.
O tun ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti kan lu igbo Onigaari fun bi ẹẹmẹta ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọdẹ ati vijilante lagbegbe naa.











