Ọdún mẹ́jọ ni ọkọ ọmọ mi kò jẹ́ ki n fojú kan ọmọ mi lẹ́yìn ìgbéyàwó - Ìyá Osinachi

Ìyá Osinachi Nwachukwu
Àkọlé àwòrán, Ìyá Osinachi Nwachukwu

Gbogbo abiyamọ ló máa ń gbàdúrà láti má fojú sunkún ọmọ, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ fún ìyá gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu tó dágbere fáyé lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ìyá náà ṣe pẹ̀lú ikọ̀ ìròyìn BBC ni ìyá náà ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lóri àwọn ohun tí wọ́n ti là kọjá lọ́wọ́ ọkọ ọmọ rẹ̀, Peter Nwachukwu, ẹni tí ọ̀pọ̀ gbà pé òun ló ṣekúpa ìyàwó rẹ̀ nítorí bó ṣe máa ń lù ú.

Nígbà tí ìyá náà ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbẹ́ ọkàn lórí irú àná tó ní, arábìnrin Madu ní òun tí ojú òun rí lọ́wọ́ ọkọ ọmọ òun kọjá sísọ.

"Láti ìgbà tí ọmọ ti fẹ ni kò ti gbádùn ayé rẹ̀ mọ́, kódà èmi gan kò gbádùn ayé mi, mi ò ró irú rẹ̀ rí láyé mi."

Ìyá náà ọdún mẹ́jọ gbáko ni òun kò fi rí ọmọ òun lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó tán, kódà ọkọ ọmọ òun kò sọ fún òun nígbà tí ọmọ òun bí àkọ́bí ọmọ rẹ̀.

Ó fi kun pé ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọmọ òun kò ṣàlàyé gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ ń rí nínú ìgbéyàwó rẹ̀ fún òun, àwọn ará àdúgbò ló wá ń jíyìn fún òun nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésì ayé ọmọ òun fún òun.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Ó ní ní ọjọ́ kan ni ọmọ Osinachi dédé pe òun lẹ́yìn tó bí ọmọ rẹ̀ ẹlẹ́kẹ̀ẹta tó sì sọ fún òun wí pé ìyà ń jẹ òun àti pé wàhálà tí ọkọ òun ń fi ojú òun rí kọjá sísọ.

Arábìnrin Madu ní lẹ́yìn náà ló pe bàbá rẹ̀ wí pé Peter sọ fún òun wí pé bí òun kò bá kúrò ní ilé òun ní ààyè, òun yóò kúrò ní òkú.

"Ìdí nìyìí tí mo fi ní kí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ mu kúrò ní ilé ọkọ rẹ̀ nígbà náà".

Abiyamo naa tesiwaju pe: "Ọdún kan àti oṣù mẹ́ta ló lò ní ilé wa ní Enugu kí ọkọ rẹ̀ tó wá bẹ̀bẹ̀ láti mú ìyàwó rẹ̀ padà sí Abuja.

Sùgbọ́n kò wu èmi àti bàbá rẹ̀ pé kó padà síbẹ̀ ṣùgbọ́n Osinachi fárígá wí pé ohun ti Ọlọ́run bá ti so pọ̀ kí ẹnikẹ́ni má ṣe tú wọn ká."

Ó sọ síwájú pé lẹ́yìn tó padà sílé ni ọkọ tún bẹ̀rẹ̀ síní lù ú bíi bàrà.

Ọkọ ọmọ kìí gba kí n wá sí ilé wọn

Ìyá náà tún tẹ̀síwájú wí pé ọkọ ọmọ òun kìí fẹ́ rí àwọn mọ̀lẹ́bí ìyàwó rẹ̀ rárá kódà bí ó bá bímọ kìí gbà kí òun wá ṣe omuugo.

Ó ní ìgbà tí òun dé ilé ọmọ òun rí lẹ́ẹ̀kan ni ìgbà tí ó rẹ òun gidi gan tí òun sì lo oṣù kan ní ilé wọn kí Peter tó lé òun kúrò nílé rẹ̀.

Bákan náà ló ìyàwó pásítọ̀ ilé ìjọsìn Dunamis ló bá ọmọ òun bẹ̀bẹ̀ kí ọkọ rẹ̀ tó gbà kí òun tó wá sí ilé wọn.

Ó ní ó sàn kí ọmọ òun má lọ́kọ ju ọkọ tó fẹ́ lọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Peter kìí fẹ rí èmi àti ìkejì mi papọ̀ - Ìbejì Osinachi

Amarachi tó jẹ́ ìbejì Osinachi ní ọkọ ìkejì òun kìí fẹ́ rí àwọn méjéèjì papọ̀ pàápàá tí àwọn bá fẹ́ kọrin.

Amarachi ní ọjọ́ kan ní Abuja tí wọ́n pe àwọn síbi orin kan, òun àti ìkejì òun ti jọ rán aṣọ tí àwọn yóò jọ wọ̀ ṣùgbọ́n irọ́ ló padà jásí nítorí Peter kò gbà kí àwọn jọ ṣeré papọ̀ ní ọjọ́ náà tó fi wá mu kúrò lójú agbo.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ọmọ ṣe ṣorí nígbà tí àwọn tún jọ fẹ́ kọrin ní ìlú Eko.

Deborah Eneche àti Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Deborah Eneche àti Osinachi Nwachukwu

Mi ò rí oorun sùn láti ìgbà tí Osinachi ti jáde láyé

Ọmọbìnrin pásítọ̀ ìjọ Dunamis International Gospel Centre, Deborah Paul Eneche ti ní òun kò rí oorun sùn láti ìgbà tí òun tí gbọ ìkéde ikú Osinachi Nwachukwu.

Deborah ní gbogbo ìgbà ní Osinachi máa ń jẹ́ ìwúrí fún òun láti túnbọ̀ súnmọ́ Ọlọ́run nígbà tó wá láyé.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Se Deborah mọ̀ nipa iya to n je Osinachi nile ọkọ?

Deborah Enenche ní òun kò fi ìgbà kankan mọ̀ wí pé Osinachi ń kojú ohun ìfìyàjẹni nínú ìgbéyàwó rẹ̀ nítorí òun kìí dá sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.

Osinachi àti ìyá rẹ̀
Àkọlé àwòrán, Osinachi àti ìyá rẹ̀

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tó súnmọ́ arábìnrin náà kò mọ ohun tó ń kojú nínú ìgbéyàwó rẹ̀ kó tó jáde láyé.

Ó ní pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí àwọn ènìyàn ti ń sọ nípa rẹ̀, o túmọ̀ sí wí pé Osinachi kò súnmọ́ àwọn ènìyàn tó le ràn án lọ́wọ́.