Yollywood: Ṣé Iyabo Ojo ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó? Wo àwọn ohun tó sọ nípa olólùfẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, IYABO OJO/INSTAGRAM
Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ bí àdánwò ni, Yorùbá sì bọ̀ wọ́n ní bí ọmọdé bá tó lọ́kọ́ ó máa ń lọ́kọ́ ni, tí ọmọdé bátó ládàá, ó máa ń ládàá ni.
Tí ó bá ti ń tó àkókò kan nínú ìgbésí ayé ọmọnìyàn, ìgbéyàwó a máa múmú lọ́kàn tọkùnrin tobìnrin.
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Iyabo Ojo ti tú àṣírí rẹ̀ wí pé òun ní olólùfẹ́ tí òun àti rẹ̀ dìjọ ń jáde ṣùgbọ́n òun kò ní ṣe àfihàn ẹni náà àyàfi tí àwọn bá ṣe ìgbéyàwó.
- Wo ohun tí Arike ṣe nínú ìjà yìí tí Màmá ESABOD ń wọ́ ọ nílẹ̀ tuurutu tèpètèpè?
- Mo tọrọ àforíjì pé mo parọ́ ìgbéyàwó! Mi ò ṣe ìgbéyàwó kankan!
- Láyé! Ẹ ò lè rí mi mọ́ nínú fíìmù Yorùbá bí ìgbà ayé Saworoide - Araparegangan
- Ǹkan ọmọkùnrin rẹ ńgbálẹ̀ kiri, gbogbo ìlú ló wà fún; Gbas gbos tún bẹ̀rẹ̀ láàrin Tontoh dike àti olólùfẹ́ rẹ̀
Iyabo Ojo ní ó dìgbà tí àwọn bá parí gbogbo ayẹyẹ ìgbéyàwó kí òun tó mú ẹni náà yọjú lórí ayélujára.
Ní ọdún 1999 ni Iyabo Ojo kọ́kọ́ ṣe ìgbéyàwó àkọ́kọ́ lẹ́ni ọdún makànlélógún.
Ọdún 1999 àti 2001 ló bí àwọm ọmọ rẹ̀ méjéèjì ṣùgbọ́n tí ìgbéyàwó náà túká lẹ́yìn tó bí ọmọ rẹ̀ kejì.
Iyabo Ojo wá ṣàlàyé pé òun àti olólùfẹ́ òun tuntun ti wà fún bí ọjọ́ mẹ́ta kan ṣùgbọ́n òun kìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nítorí ẹni náà kò fẹ́ràn láti máa wà lórí ayélujára.
- Igboho ti dé padà! òòsà dé! mi ò sàìsàn! kokoko lára le - Sunday Igboho
- Ìtàkùn àpapọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná 'National grid' ní Nàìjíríà tún ti paná pi
- Ẹkùn sọ bí ìròyìn ikú gbajúgbajà olórin ẹ̀mí tó kọ orin 'Ekwueme' ṣe jáde
- Tóò bá so síìmù MTN, Glo, Aitel àti 9mobile rẹ pọ̀ tí wọ́n sì tún gbégi lé síìmù rẹ, wo ohun tóo lè ṣe
- Ọ̀rọ̀ ''Zoning'' ipò ààrẹ ní Naijiria dàbí àgbàlàgba tí wọ́n ń fún ní ''baby Formula'' - Dino Melaye
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Ọmọ Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀èdè mìí kò ní l'ánfàní láti ra ilé sí Canada mọ́ o! ìdí nìyí
- À ǹ gbìyànjú láti yánjú àáwọ̀ àárín ẹgbẹ́ wa, àmọ́ àwọn èèyàn ló bẹ̀ mí kí n lọ fún sáà kejì
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ẹ̀sùn mẹ́jọ nínú mẹ́ẹ̀dógún tí wọ́n fi kan Kanu
- Ẹ wo àwọn ǹkan tó ń fàá tí àwọn kan kò lè ṣe láì ní ìbálòpọ̀ lemọ́ lemọ́ láì sinmi
"Olólùfẹ́ mi gbàgbọ́ wí pé bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń bú mi lórí ayélujára ti pọ̀jù, kò sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ tún wá mú òun papọ̀ mọ́ gbogbo èyí tí wọ́n máa ń ṣe fún mi".
''Ó jẹ́ ẹni tí kò fẹ́ràn láti máa wà lórí ayélujára, ó fẹ́ràn láti máa gbé ara rẹ̀ pamọ́".
Njẹ́ Iyabo Ojo ń gbèrò láti tún ṣe ìgbéyàwó mìíràn?
Iyabo Ojo ní kí òun tó le gbé ẹnìkan gẹ̀gẹ̀ láti ṣe àfihàn ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ lórí ayélujára, á jẹ́ wí pé àwọn ti ṣe ìgbéyàwó.
Ó làá mọ́lẹ̀ wí pé òun kò rò wí pé ó ṣeéṣe fún òun láti gbèrò tàbí dámọ̀ràn dídán ilé ọkọ wò mọ́.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ẹnìkan tí àwọn jọ ń ṣeré ìfẹ́, òun kò gbàá lérò láti tún máa ṣe aya ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ọkùnrin kan.
Bákan náà ló ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kìí sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ olólùfẹ́ òun àmọ́ òun ní ẹni tí òun ń fẹ́.
"Báwo ni ọmọbìnrin tó rẹwà bí tèmi kò ṣe ní ní ọkùnrin kan nínú ayé rẹ̀."


















