NIN: Tóò bá so síìmù MTN, Glo, Aitel àti 9mobile rẹ pọ̀ tí wọ́n sì tún gbégi lé síìmù rẹ, wo ohun tóo lè ṣe

Aworan awọn eeyan to pejio siwaju ọfisi NIMC ni ọjọ Keje oṣu Kẹrin ati afihan siimu

Awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni korajọ si ọfiisi ti wọn ti n forukọ silẹ fun nọmba NIN jakejado Naijiria.

Eyi waye lẹyin ti ijọba ṣe agbekalẹ aato ati ofin lati gbẹsẹ ofin le awọn ẹrọ ibanisọrọ ti wọn ko tii so nọmba siimu wọn pọ mọ NIN.

Ajọ to n ri si ibaraẹnisọrọ ni Naijiria ninu atẹjade kan lọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin pa aṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ to n ri si ibaraẹnisọrọ ki wọn gbegi le siimu ti wọn ko tii fi orukọ silẹ tabi so o pọ mọ NIN.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Lẹsẹkẹsẹ naa ni awọn ileeṣẹ bẹrẹ si ni gbe igbesẹ naa. Lati igba ti ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti ko tii so siimu wọn pọ mọ nọmba wọn ti n ni iriri pe wọn ko ribi pe jade lori ipe yii.

Aworan awọn eeyan to pejio siwaju ọfisi NIMC ni ọjọ Keje oṣu Kẹrin

Niwọn igba ti wọn ti bẹrẹ ṣiṣe amuṣẹ ilana ofin yii lori eeyan miliọnu marunlelaadọrin to n lo foonu ti o si ti n pa wọn lara gẹgẹ bi awọn alamojuto ibanisọrọ ṣe sọ.

Sugbọn o da bii pe ṣiṣe amuṣẹ ofin yii naa tun ṣe akoba fun awọn mii naa ti wọn ṣi ti so nọmba wọn pọ mọ NIN ti wọn ko ṣi le pe ipe sita.

Lootọ ẹni to ba ti so siimu pọ mọ NIN nilo lati gba esi aridaju latọdọ awọn ileeṣẹ ibanisọrọ pe o ti pari igbesẹ naa.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Amọ, awọn mii to n lo foonu ni awọn pari rẹ sibẹ wọn ko gbọ esi nigba ti awọn mii si ni awọn tilẹ gbọ esi amọ wọn tun gbegi le siimu awọn.

Akọṣẹmọṣẹ kan nileeṣẹ ibanisọrọ ṣalaye ohun to lee mu ki iforukọsilẹ eeyan kan ma pari:

  • O ṣeeṣe ko jẹ pe iforukọsilẹ naa ko pari rara
  • Ṣegeṣege ẹ̀rọ kọmputa naa lee fa a
  • Boya wọn ti so NIN ọhun pọ mọ nmba pupọ ju
  • Bi ko ba si ifọwọsowọpọ to yanranti lori ayelujara latọdọ ajọ NIMC
  • Iṣoro oju itakun agbaye

Ki wa lo lee ṣe?

Akṣẹmọṣẹ ọhun ni ohun ti ẹni ti ọrọ yii ba kan le ṣe ni ko kọkọ lọ si ọfiisi ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ eyi ti o n lo.

Bakan naa lo ni ajọ Telcos tii ṣe apapọ gbogbo awọn ileeṣẹ kii fẹ ki siimu eeyan kankan di gbegi le tori ko pe wn.

"O maa n jẹ ka padanu owo ati ere to n wọle ni".

O wa ṣalaye pe awọn awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilo onibara to pọ gidi.

Lati ma si jẹ ki wọn padanu onibara, wọn n tẹsiwaju lati rọ awọn eeyan ki wọn wa si ọfiisi wọn.

Murtala Muhammed to jẹ adari ajọ NIMC ti Masalacin Murtala ni Kano naa fi aridaju ọrọ yii han.

O sọ fun BBC pe: "Bi wọn ba gbegi le siimu rẹ, lọ taara si ọfiisi ileeṣẹ siimu naa lati sọ fun wọn.

Ileeṣẹ Telco naa yoo fun ni iwe ti oo mu lọ si ajọ MINC lati ibẹ ni wọn yoo ti gbe ọrọ rẹ lori lọdọ ikọ to n bojuto akọsilẹ wọn".

Ohun too nilo lati foruk silẹ

Aworan afihan siimu

Oríṣun àwòrán, Other

Too ba ti fẹ forukọ NIN rẹ silẹ lorii foonu rẹ ohun too nilo niyii:

  • Nọmba foonu rẹ
  • Orukọ rẹ lẹkunrẹrẹ
  • Nọmba NIN rẹ (eyi too le yẹwo nipa lilo *346#)
  • Atẹjiṣẹ Email rẹ
  • Ọjọ ibi rẹ

Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ Nọmba MTN

Lọ si oju opo ti NIN ṣi fun onibara lati ṣe e https://mtnonline.com/nin/

  • Oo nilo fọọmu ti oo kọ orukọ rẹ si
  • Kọ nọmba MTN rẹ sibẹ
  • Kọ NIN rẹ sibẹ
  • Kọ adirẹsi Email rẹ

Tẹ bọtini ti wọn kọ SUBMIT si

Bakan naa o le tẹ nọmba *785#

Ẹrọ foonu rẹ yoo beere pe ko kọ nọmba idanimọ NIN rẹ ko si tẹ ẹ jiṣẹ.Yoo sọ fun o pe o ti pegede nigba to ba fi ranṣẹ tan.

Ti gbedeke ba kọja ti siimu rẹ ko ni nọmba NIN to so mọ, wo nkan ti yoo tun ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ NọmbaGLO

Kọ ọrọ Update NIN (fi alafo si) NIN (alafo) Orukọ rẹ akọkọ (alafo) ati orukọ baba rẹ si nọmba 109.

Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ NọmbaAirtel

Igbesẹ naa lọ bayi nipa titẹ *121*1#

  • Kọ nọmba idanimọ NIN rẹ
  • Lẹyin naa wa ri atẹjiṣẹ pe o ti yege

Too ba fẹ́ so NIN pọ mọ Nọmba 9 Mobile rẹ

  • Kan si oju opo https://9mobile.com.ng/nin
  • Tẹ aaye alawọ ewe ti wọn kọ ọrọ 'verify and link your NIN now'

Ileeṣẹ to n risi ibaraẹnisọrọ ati eto ọrọ aje ayelujara Naijiria ti paṣ pe ki gbogbo awọnb ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ wgile gbigba owo ogun Naira ki awọn eeyan to le ri nọmba NIN wọn yẹwo.

Wọn lawọn gbe igbesẹ yi ki eto riri nọmba NIN awọn eeyan baa le rọrun.

Eyi tunmọ si pe gbogbo ọmọ Naijiria lo le tẹ *346# lọfẹ ti wọn ba fẹ wo nọmba NIN wọn.