NIN: Nọ́mbà fóònù tí kò so mọ́ NIN kò lè pè síta béẹ́, aráàlú ní àwọn tí so ó pọ̀ ṣùgbọ́n kò ṣiṣẹ́

Njẹ wọn o mu ileri ṣẹ abi wọn o ni mu ṣẹ lọpọ ọmọ Naijiria n beere lẹyin ti ijọba kede pe awọn yoo gbegi di foonu awọn ti ko so NIN mọ nọmba foonu wọn.
Wakati mẹrinlelogun lẹyin ti wọn ni awọn yoo bẹrẹ igbesẹ yi, ọpọ lo ti n lọgun pe awọn ko ribi pe jade lori nọmba wọn amọ ipe n wọle.
Nigbati BBC ba awọn alabara awọn ileeṣẹ ibanisọrọ kan sọrọ, wọn ni kini naa bẹrẹ bi ere lọjọ Karun oṣu kẹrin tii ṣe ọjọ kan lẹyin ọjọ ti ijọba ni ki igbesẹ yi bẹrẹ.
- Ìjọba pàṣẹ fún àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti fi òfin de ìpè lórí fóònù àwọn tí kò so NIN mọ́ nọ́mbà wọn
- Mínísítà ìbaraẹnisọ̀rọ̀ ti sún ìsopọ̀ NIN àti SIM di June 30
- Ǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa NIN àti BVN
- Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ìsúnsíwájú ọjọ́ ìforúkọsílẹ̀ nọ́mbà NIN
- Buhari, pàṣẹ fún Pantami kó lọ tọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ lórí ìforúkọsílẹ̀ NIN-SERAP
Arakunrin Dara Onipede ti BBC ba sọrọ sọ pe lori nọmba meji ti oun ni, ọkan pere ni ipe ti n jade nibẹ ti oun ko si ri ipe pe jade lori ẹlẹẹkeeji.
O ni airi ipe pe yi ti mu ki oun yi soju nọmba ẹlẹẹkeeji lati maa fi ba awọn eeyan sọrọ.
Nigba ti a beere lọwọ rẹ boya ko so nọmba yi papọ mọ nọmba NIN rẹ bi ijọba ti ṣe ni ko ṣe, Dara ni mejeeji ni oun so pọ.
- Òjò èpè! Tá ló dáa lẹ̀ láàrin Lizzy Anjorin àti Granma Florida, ESABOD tí àṣírí títú yìí ṣe ń gún wọn lára?
- Láìsì nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN ní 2020; kò sí ìdánwò- JAMB
- 'Ẹ wòó kò jọọ́, èmi kò lè so nọ́mbà fóònù mi mọ́ NIN tíjọba Nàìjíríà ń gbé kiri'
- Njẹ́ o mọ pé N3000 ló o sàn láti gbà kaadi ìdánimọ̀ míì bí tí tẹ́lẹ̀ bá sọnù?
''Nọmba mi mejeeji ni mo so papọ mọ NIN mi nigba ti wọn kọkọ kede pe ki a so awọn nọmba wa papọ. Koda mo tori rẹ download appu NIMC si ori foonu mi''.
O ṣi aapu NIMC fun wa lori foonu rẹ to si fi aworan aaye ibi ti wọn ti jẹri si pe o ti so awọn nọmba yi papọ.
Ninu nkan ti wọn kọ sibẹ, wọn ṣapejuwe meji lori ipo tawọn nọmba rẹ mejeeji wa.
Akọkọ ohun to wa nibi nọmba rẹ akọkọ ni ''validated'' eleyi taa le tunmọ si pe wọn fontẹ lu u.
Ẹlẹẹkeeji ohun taa ri nibi nọmba rẹ ẹlẹẹkeeji ni ''Verified'' ti itumọ rẹ naa jọ pe wọn ti jẹri sii pe nọmba yi ti so pọ mọ NIN rẹ.
Ohun to ruju fun Dara ni pe nọmba ti wọn kọ validated fun ni ko pe sita amọ eleyi ti wọn kọ verified si lanfaani lati pe sita.
Oun nikan kọ ni iru nkan bayi n ṣẹlẹ si. Arakunrin Iyanda Olanrewaju naa jẹri si iru nkan bayi loju opo appu NIMC rẹ.
Bo ṣe n ṣẹlẹ si Dara ti ko ribi pe sita lori nọmba rẹ kan, Iyanda naa ko ribi pe jade lori nọmba Glo rẹ ti wọn kọ ọrọ validated si iwaju rẹ.
Bẹẹ wa ni ọrọ ri fun ọpọ ọmọ Naijiria to n sọrọ loju opo Twitter pe awọn ti so awọn nọmba yi papọ mọ NIN wọn laimọye igba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ijọba ti sun ọjọ siso siimu mọ NIN siwaju lẹẹmẹẹsan, araalu naa si lawọn ti ṣe e laimọye igba
Lori ọrọ siso siimu mọ nọmba idanimọ NIN yi, bi a ba ka ni meni meji, o kere tan ijọba ti sun eto yi faraalu ni nkan bi igba mẹsan.
Loṣu Kejila ọdun 2020 ni ijọba Naijiria kọkọ kede ilana pe awọn ti ko ba so NIN wọn mọ siimu wọn ko ni le pe lori ago wọn.
Wọn gbe igbesẹ yi nigbana lati koju ipenija aabo ti o koju Naijiria nipa pe awọn alaburu a maa lo siimu aimọye lati fi hu iwa aburu.
Irori ijọba ni pe bi wọn ba so siimu wọn mọ NIN, awọn yoo le tọ pinpin ni to ba lo nọmba yala lati fi huwa gbajuẹ tabi iwa aburu mii bi ijinigbe.
Ọpọ araalu gbiyanju lati tẹlẹ aṣ yi ṣugbọn nitori ipenija airibi ṣe lab awọn ileeṣẹ ibaranisọrọ, ijọba ni awọn yoo sun ọjọ naa siwaju.
Sisunsiwaju yi ni wọn ṣe titi to fi kan elyi to waye kẹyin ti gbedeke rẹ pe ni ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta,
Ọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin ni ijọba pa awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ laṣẹ tuntun yi pe ki wọn ja ipe sita lori foonu ẹni ti ko so siimu rẹ pọ mọ NIN.
Ni iroyin to tẹwa lọwọ, o kere tan miliọnu mejilelaadọta ọmọ Naijiria ni siimu wọn faragba ninu airibi pe sita yi.
Ninu awọn ti wọn ti tẹle aṣẹ ijọba, ohun taa gbọ ni pe wọn fi siimu marundinlaadoje sọwọ fun isopo ti miliọnu mejidinlọgọrin si ti wa ni siso pọ.
Bawo ni o ṣe le so nọmba foonu rẹ mọ NIN?

Oríṣun àwòrán, Other
O le lọ si awọn ibudo ti ijọba fi ọwọ si lati gba NIN rẹ.
Lẹyin naa ni waa so mọ nọmba foonu rẹ nipa lilo oju opo ti ajọ NIMC ati awọn ileesẹ ibanisọrọ la kalẹ.
MTN - *785#
Glo - 109 nọ́mbà NIN rẹ#
Airtel - *121*1#
Etisalat - *996#
O si tun le lo ori ayelujara 'App' àjọ NIMC.















