Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni, àṣé...

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

"Titi to fi de oju mi ni afẹfẹ inu Taya náà fa yọ, "artificial ni wọn gbe sibẹ bayii, koda ninu ẹyin oju keji, ida mẹẹdogun ninu ọgọrun nikan ni mo fi n riran".

Ifarapa ati ipadanu ti baale ile ati ọmọ rẹ ni ko ṣee fẹnu sọ latari taya ọkọ Tirela kan to ta pau mọ awọn mejeji lọwọ lasiko ti wọn n ṣiṣẹ lori rẹ.

Ọjọ́ burúkú èṣù gbomimu ni ọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ninu oṣu Kọkanla ọdun 2019 fun idile arakunrin Seye Malaolu ti wọn n gbe nilu Abeokut, ipinlẹ Ogun.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, ati baba ati ọmọ ṣalaye bi ile aye wọn ṣe di omii porogodo ati titi ayeraye.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

"Oju kan naa ti mo gbọwọ si lara taya tirela yẹn ni ọmọ mi naa gbe ọwọ si afi gbàùù taa gbọ́, mi o mọ ibi ti mo wa mọ".

Yatọ fun Seye, ọmọ rẹ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun Fisayo naa kagbako iṣẹlẹ ti awọn mejeji ni awọn ko le gbagbe laelae.

Fisayo naa ṣalaye bo ṣe ranti bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ati titi wọn fi ge ọwọ oun ati baba rẹ ti ẹsẹ oun funrarẹ si ti di kọndẹ.

Wọn jọ ṣalaye bi eeyan kan ṣe gbe taya ọkọ Tirela wa fun wọn lati tun tun ṣe ati bi awọn dokita ṣe ge ọwọ awọn mejeji.

Nibayii, titi de oju, eti ati ẹsẹ ni iṣẹlẹ ọhun ti pa lara ti seye si ni awọn ti na owo to le ni Miliọnu meje lori itọju toun ti gbogbo dukia ti wọn ti ta to si jẹ pe itọju ara wọn ṣi n tẹsiwaju.