Sheikh Nuru Khalid: Imáàmù táwọ́n aláṣẹ́ dá dúró ti ríṣẹ́ míì tó ta lẹ́nu

Sheik Nuru Khalid

Oríṣun àwòrán, Sheik Nuru Khalid

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ṣẹ́ẹ mọ̀ pe Yoruba ni "bi wọn ṣe n ṣe nilee wa, eewọ ibomii ni lo mu oriire ba Imaamu Nuru Khalid to sọrọ si aarẹ Buhari to si tori rẹ gba idaduro ni Mọṣalaṣi.

Imaamu Mọṣalaṣi to wa ni agbegbe Apo Legislative Quartres ni Abuja eyi to ṣẹ gba idaduro iyẹn Sheik Nuru Khalid ti riṣẹ mii bayii.

Iroyin ni awọn alaṣẹ ati oludari Mọṣalaṣi Jumaa tuntun kan ni Area 11 ni ẹyin Banki apapọ Naijiria ti ni ko bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ ni Jumaa ọjọ Jimoh to n bọ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Khalid gba idaduro lẹyin to sọ ọrọ alufansa si Aarẹ Muhammadu Buhari nitori ikọlu si ọkọ oju irin to ṣlẹ lọjọ Aje to kọja ni ọna Abuja si Kaduna.

Ẹwẹ, oun funrarẹ ṣapejuwe idaduro rẹ gẹgẹ bi ara ifarada to oun ni lati la kọja pe oun ni imọlara iya to n jẹ awọn araalu ati pe o sọ otitọ. Khalid fi ọrọ sita pe "nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, n o maa dari awọn olujọsin mi ni ọjọ Ẹti yii, nitoripe gẹgẹ bii adari ẹsin, a nilo ibi kan lati maa darapọ mọ".

Bí wọ́n ṣe yọ ìmáàmù Mọ́ṣáláṣí Apo, Sheik Nuru

Sẹnetọ Saidu Dansadau to jẹ alaga igbimọ Mọṣalasi Apo, niluu Abuja ti sọ pe awọn ti da Sheik Muru Khalid duro lẹyin ti wọn ti kọkọ ni ko lọ rọọkun nile ṣaaju.

Sẹnetọ Dansadau ṣalaye fun BBC pe awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti Imaamu ọhun kọ lati tuba lẹyin awọn ọrọ to sọ ninu waasi rẹ lọjọ Ẹti.

Ninu iwe idaduro ti wọn fi ranṣẹ si Imaamu naa, wọn ni awọn ṣawari pe ko kabamọ ohun to ṣe lẹyin ti wọn ni ko lọ rọokun nile, eredi ree ti ijiya rẹ fi gbe pẹẹli si.

Lẹta ọhun ka pe "Sheik, iwọ funra rẹ mọ ohun ti ẹsin Islam sọ nipa ibọwọfun ati eto."

"Amọ iha ti o kọ si bi a ṣe ba ọ wi lori awọn ọrọ ti o sọ fihan pe o ko kabamọ ohun ti o ṣe."

Ki ni ẹṣẹ Sheik Nuru Khalid?

Ọjọ Ẹti, to jẹ ọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii ni Imaamu naa sọrọ nipa ikọlu ọkọ oju rin to waye ni ipinlẹ Kaduna.

Ninu waasi naa lo ti sọrọ tako ijọba apapọ lori ikuna rẹ lati bojuto eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Fake pastors:

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ni awọn agbesumọmi kọlu ọkọ oju irin naa to n lọ lati ilu Abuja si Kaduna, nibi ti wọn ti pa eeyan mẹjọ, ti wọn si tun ti ji awọn mọkanlelogun mii gbe.

Amọ lọjọ Aje, Imaamu naa sọ fun ileeṣẹ iroyin BBC pe oun ko kabamọ ọrọ ti oun sọ.

O ni o dun oun lọpọlọpọ pe alaga igbimọ to gba iṣẹ lọwọ oun yii jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Zamfara, nibi ti ko si abo kankan nibẹ.

Sheik Muru Khalid fi kun pe Ọlọrun nikan lo maa n gbe eeyan de ipo giga ati pe oun ko ni dẹkun lati maa sọ ootọ.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ìmáàmù Abuja tó takò ààrẹ Buhari nínú ìwàásù rẹ̀ gba ìdádúro, àlàyé rèé

Aworan Imam Khalid

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Awuyewuye ti n waye lori ayelujara lẹyin ti awọn alaṣẹ mọṣalaasi kan ni Apo, nilu Abuja da imaamu mọṣalaṣi naa duro.

Ọjọ Ẹti ni iroyin sọ pe Sheikh Nuru Khalid sọ ninu waasi rẹ pe ko dara bi aarẹ Buhari ṣe kọ lati lọ si ipinlẹ Kaduna lẹyin ikọlu awọn agbesunmọmi si ọkọ reluwe.

Kaakiri loju opo ayelujara ni ọrọ yi ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa ti awọn ọmọ Naijiria si ni o ku diẹ kaato pẹlu bi wọn ṣe da imaamu yi duro.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ
Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

Ikọlu to mẹnu ba ninu iwaasu rẹ jẹ eleyi to n kọ awọn araalu lominu nitori iye ẹmi to ba lọ.

Nilu Kaduna ni awọn agbesunmọmi ajinigbe ti da ọkọ reluwee lọna ti wn si sọ ado oloro si oju irin.

Ninu ikọlu yi, o kere tan eeyan mẹjọ ni ijọba sọ pe o padanu ẹmi wọn ti awọn ọpọ si farapa.

Titi di ba ṣe n sọrọ yi awọn eeyan kan wa ti wọn ko mọ ibi tawọn ajinigbe gbe wọn salọ.

Gomina Kaduna ti n tori ọrọ yike gbajare to si ni awọn ologun Naijiria ko ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ ni lati koju awọn janduku ajinigbepawo yi.

Ki lawọn eeyan sọ nipa idaduro imaamu Nuru Khalid?

Loju opo Twitter niṣe ni awọn eeyan n da si ọrọ aṣẹ lọ rọọkun nile ti igbimọ mọṣalasi Apo gbe kalẹ fun Imam Khalid.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

@farooqkperogi to jẹ alatako ijọba aarẹ tun alaye ọrọ Imaamu naa sọ nibi to ti ni ko bojumu bi aarẹ ko ṣe kan si ilu Kaduna nitori nigba to nilo ibo wọn, o lọ sibẹ.

Gimba Kakanda ti oun naa jẹ onwoye lori ọrọ to kan orileede Naijiria da si ọrọ yi to si ni awọn eeyan a mu bu awọn olori ẹlẹsin pe wọn gbe lẹyin ijọba ṣugbọn eeyan kan re ti o sọrọ tako ijọba

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Sẹnẹtọ Sheu Sani to fi igba kan ṣoju ipinlẹ Kaduna nile aṣofin agba kesi awọn igbimọ mọṣalasi Apo lati yi aṣẹ yi pada.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Kini ẹsun ti Igbimọ Mọsalaṣi fi kan Imam Khalid?

Ninu iwasuu ọjọ Jimọ rẹ to ṣe niṣe ni Imaamu Nuru Khalid bẹnu atẹ lu ijọba Naijiria lori ailekoju ipenija aabo ati ipaniyan to n koju Naijiria.

Ninu iwaasu rẹ, o gba araalu nimọran lori awọn igbesẹ ti wọn le gbe lati fẹhonu han si aiṣedeede ijọba nipa ipeese aabo fun araalu.

O gbawọn nimọran pe ti ijọba ko ba dẹwọ ipaniyan to n waye, ki araalu ma ṣe jade dibo.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC pẹlu alaga igbimọ Mọṣalasi naa, ṣẹnẹtọ Saidu Muhammad Dansadau sọ pe awọn da imaamu naa duro nitori ọrọ iwaasu to le da wahala silẹ.

Atẹjade ti wọn fi sita ni iwaasu Imam Khalid tako ẹsin Islaamu ti wọn si ni awọn ti yan imaamu mi ti yoo rọpo Imam Khalid