Woman shows up months after her burial: Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú obìnrin tó dédé yọ sí ìlú lẹ́yìn tí wọ́n ti sìnkú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Eemọ luputu pẹlẹbẹ lariwo to gbòde kan bayii nigboro ìlú tí kàyéfì yìí tí ṣẹlẹ̀ bí arabinrin kan to jẹ ọ̀dọ́-langba ni ilu Lindi ti gbogbo araalu ni o ti ku ṣe dede yọju laarin ilu rẹ pada.
Wọn ti fi aridaju ikú, ìsìnkú àti idagbere ìkẹyìn tí wọn ṣe fún un hàn ko to tun dédé yọjú padà sì ìlú rẹ o! Ẹyin naa pe "kayeefi".
Iroyin yii ti kọja ilu to ti sẹlẹ nikan, o ti tàn ká gbogbo orileede Mozambique.
Gẹgẹ bi ìròyìn ṣe sọ, inu osu Kọkànlá ni eto isinku arábìnrin náà waye.
Awọn ara ilu Lindi naa n ṣàpèjúwe àti alaye pe Eurélia Manuel Benjamim ti jinde kuro ni ipo oku o si ti di alaye.
Ọrọ wo ni Eurélia Manuel sọ jáde lẹ́nu?
Nigba ti gbogbo èèyàn ń kọ ha ha jade lẹ́nu, Eurélia ni tìrẹ sọ pe ṣe ni oun lọ ṣiṣẹ́ ni oko aburo baba òun fun oṣù díẹ̀.
Èèyàn kan lára àwọn eekan Aláṣẹ ilu ni ẹkùn Montepuez sọ fún àwọn oniroyin Ìpínlẹ̀ náà pé "ohun gbogbo ni wọn ṣe pérépéré nínú ètò ìsìnkú Eurélia - kódà ó tún ni lọjọ kẹta, wọn ṣe ibewo si ibojì rẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ní ibojì náà ṣì wá ní títì paa".
Ọ̀rọ̀ naa so si ni lẹ́nu gbaa. Kódà onírúurú ni ọna ti ọ̀rọ̀ náà tí di èyí tí wọn ń gba bí ẹni ngba igba ọtí.
Ẹwẹ, ìjọba tí rán ikọ̀ awọn akosemose lọ sí ìlú Lindi láti tán iná wádìí òtítọ́ ọrọ yìí láti lè mọ okodoro ọrọ.
















