Kaduna-Abuja train attack: El-Rufai sọ iṣẹ́ táwọn ológun ilẹ̀ òkèèrè yóò ṣe

Oríṣun àwòrán, @El Rufai
Gomina Ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai ti búra pe awọn ikọ ologun ilẹ̀ okeere ni oun yoo ko wọ Naijiria lati wa koju awọn tó ṣe ikọlu lalẹ ọjọ Aje si ọkọ ojú irin tó ń ná Abuja si Kaduna.
Bákan naa lo fi kún un pé ìlú mẹrin míì lára àwọn tó wà ní ìhà Àríwá-Ìwọ Oòrùn ìyẹn Katsina, Zamfara, Kebbi àti Sokoto leè dára pọ mọ oun láti fi koju àwọn onise aburu to ṣe ikọlu náà "bí ijọba ba kọ tí wọn kò fòpin sí iṣẹlẹ idunkoko mọ rẹ.
Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, àwọn agbebon ṣe ikọlu náà to mu ẹ̀mí awọn eniyan lọ toripe ijoba ko ṣàtúnṣe to yẹ.
El-Rufai ṣipaya èyí fáwọn ara ile igbimọ asoju/sofin lẹyin ibewo tìrẹ sí ilé Ààrẹ láti tubọ fún un ní àbọ̀ lórí iṣẹlẹ náà.
Kí lóde tí wọn kò tíì rí àwọn tó gbebon náà pa?
Àti pé, nibo làwọn Sójà Naijiria wa? Èyí àtàwọn ìbéèrè míì lo n jade táwọn èèyàn fẹ́ mọ.
"Ìdí ẹ gan niyii tí mo ṣe lọ rí Ààrẹ Buhari. Bákan náà, mo ti ní bí wọn kò bá gbé àwọn igbese yìí, ó ti di dandan kí àwa gomina bẹ̀rẹ̀ si ni dáàbò bo àwọn aráàlú wá kódà tó bá di pé kí a kò àwọn ológun wọlé láti orileede míì".
El-Rufai ni bi àwọn ọdọ Naijiria bá kùnà, "mo fi Ọlọ́run búra, ohun taa ṣe nìyẹn torí ọrọ yìí tí kọjá afenuso.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iṣẹlẹ ọjọ Aje yẹn i bá má ṣẹlẹ̀ kani pé ìjọba gbọ́ sì òun lẹ́nu ni fún ikilọ ṣáájú àkókò náà.
Bákan náà ni iforowanilenuwo kan to sọ lédè Hausa, gomina naa ṣàlàyé pé Ààrẹ Buhari wá leyin erongba oun.
El-Rufai ni àwọn ikọ̀ Boko Haram lọ ṣe ikọlu náà. "A gbọ́ esi pé wọn ti wo inú reluwee náà tí wọn sì ń gbiyanju lati jẹ ko gbiná".
Ó ní àwọn kò lẹta sí awọn leemeji amọ pàbó lo ja si.
Kí ni alaye ikilọ tí El-Rufai ṣe fún Buhari láti dáwọ Irina ojú irin yìí dúró ṣáájú àkókò yìí?
El-Rufai ni "ni tiwa, iṣlẹ yii waye tori a ti kọ lta si ileeṣẹ Reluwee lẹẹmeji pe ki wn dawọ irin alẹ tori iroyin taa gbọ nipa eto aabo latọdọ Boko Haram pe wọn n gbiyanju lati jo ọkọ oju irin ṣugbọn wọn ko gbọ.
Bakan naa wọn tabuku awọn Ileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu pe wọn kọ bareke kan si Katari nibi ti ọkọ baalu le balẹ si tori pe ti nkankan ba ṣẹlẹ ki wọn lee koju rẹ amọ wọn ṣii tori ọpọ ọkọ hẹlikọputa kii fo loru "tori naa la fi gba ijọba nimọran pe ki Reluwee ma rinrin alẹ ṣugbọn ijba ko gbọ".
















