Dejo Tunfulu: Ọ̀gá Bello ní olóògbé náà kìí kọjá ààye rẹ̀, ọmọ dáadáa ni

Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, dejomania/Instagram

Awọn agbaagba osere ti n sedaro akẹẹgbẹ wọn to jade laye, Kunle Adetokunbo, ti ọpọ eeyan tun ọ si Dejo Tunfulu.

Ọkan lara awọn agba osere tiata ti iku Dejo Tunfulu ka lara pupọ ni Adebayo Salami ti ọpọ eeyan mọ si ọga Bello.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iku oloogbe naa, ọga Bello ni iku Dejo Tunfulu ba awọn nibi ti ko dara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga Bello ni ko ju isẹju mẹwa ti oun gbọ nipa iku oloogbe ti a fi kan si oun, to si han ninu ohun rẹ pe inu rẹ ko dun rara.

"Gbogbo nnkan to wa ni akọsilẹ pe mo fẹ se lonii, ni iku Dejo ti jẹ ki irẹwẹsi ba mi lori wọn, n ko tiẹ mọ nnkan ti mo fẹ se.

Mo wa n gbadura pe Ọlọrun yoo ba wa tẹ si afẹfẹ rere, ko si ni se iku rẹ ni akufa.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Dejo Tunfulu kii kọja aaye rẹ:

Nigba to n sọ ohun to mọ nipa oloogbe ati isesi rẹ loke eepẹ, ọga Bello ni "ọmọ daadaa ni Dejo Tunfulu.

O ni irẹlẹ, o ni itẹriba, to si n pa ofin mọ, bẹẹ ni kii kọja aaye rẹ rara ati rara, afi ki Ọlọrun saanu wa."

Bakan naa ni ọga Bello sisọ loju rẹ pe oko ere ti awọn ẹgbẹ osere ti n ya isẹ lawọn wa, ti awọn si n gbero lati pa awọn isẹ tawọn

Amin iyasọtọ kan

Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa Dejo Tunfulu tó jáde láyé

Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, dejomania/Instagram

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Kunle Tokunbo tí gbogbo ènìyaǹ mọ̀ sí Dejo Tunfulu ti jáde láyé.

Ni oru mọjumọ ọjọbọ si ọjọ Ẹti ni oloogbe naa jade laye bi o tilẹ jẹ pa a ko tii le fidi ohun to se okunfa iku rẹ mulẹ.

Aadọta ọdun ni loogbe naa lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Yàtọ̀ sí Kunle Afod tó kéde ikú Dejo Tunfulu lórí Instagram rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ bíi Kemi Korede náà ti fi ìkéde ikú Dejo soju opo Instagram wọn

Kunle Afod kọ wí pé "Haaaa, eléyìí burú jáì, Daddy Junior, mi ò tí gbàgbọ́" to si ni iku rẹ ba oun lojiji

Bákan náà ni Kemi Korede kọ wí pé "Hmmmm bọ̀dá Kunle, ilé ayé ilé asán, Ọlọ́hun tí kò ṣe bi lẹ́jọ́, ọ̀run rere"

Ikede iku Dejo Tunfulu ti Kunle Afod se

Oríṣun àwòrán, kunleafod/Instagram

Ki lo pa Dejo Tunfulu?

Bi o tilẹ jẹ pe BBC Yoruba si n se iwadii kaakiri lati gbọ okodoro ọrọ nipa ohun to seku pa gbajumọ osere tiata naa.

Amọ ohun ta gbọ ni pe titi di aarọ ana, aya rẹ ya gaga, ti ko si si ifura pe ọlọ ti de si.

Amọ ẹnikan to ba BBC sọrọ, to fẹ ka fi orukọ bo oun lasiri ni irisi Tunfulu ti fihan pe aisan nla n see.

O ni osere tiata naa ru pupọ, to si n gbẹ si lojoojumọ bi o til j pe ko fi bẹẹ ni omi lara lati ilẹ.

Bẹẹ ba si gbagbe, wọn ti gbe iroyin kan sita lọdun 2014 pe Dejo Tunfulu jade laye.

Iroyin naa ni Dejo Tunfulu, nígbà tó ń ya sinimá náà bẹ̀rẹ̀ sí ní húkọ́, tó sì ń pọ ẹ̀jẹ̀ lẹ́nu, tí wọ́n sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn LUTH tó wà ní Ikeja.

Gẹ́gẹ́ bí iroyin naa se wi, ìwádìí ti fi hàn pe Dejo Tunfulu ti ní àìsàn kan tó ń ba fínra nínú imú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò tètè tọ́jú rẹ pẹ̀lú èròńgbà wí pé aisan naa kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́.

Àkọlé fídíò, Gbọ́ ohun ti àwọn òṣèré tíátà Yoruba sọ fún BBVC nípa Baba Suwe

Ohun mẹjọ pataki nipa Dejo Tunfulu:

Kunle Adetokunbo ni orúkọ tí ìyá àti bàbá rẹ̀ sọ́ ṣùgbọ́n tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dejo Tunfulu ninu ere tiata.

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún, ọdún 1972 ni wọ́n bi Tunfulu ní Idumota, Lagos Island, nipínlẹ̀ Eko.

Ọmọ bíbí ìlú Ikija, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ni.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ansar-Ud-Deen, Lagos Island, lẹ́yìn èyí ló lọ sí Modern Way Nigeria School of Printing níbi tó ti gbàwé ẹ̀rí nípa ìmọ̀ ìtẹ̀wé.

Ipa adẹ́rìnínpòṣónú ló máa ń kó nínú eré sinimá tó sì máa ń kílòlò nínú eré.

Sinimá Omo Oran ló fi di gbajúgbajà èyí tí òun àti Lalude jọ ṣe.

Ní ọdún 1987 ló kọ́kọ́ ṣeré lórí amóhùnmáwòrán nígbà tó kópa nínú eré ọlọ́sọ̀ọ̀ṣẹ̀ Apere Ijogbon èyí tí ikọ̀ Kolawole International Theatre Group máa ń gbé jáde.

Ní ọdún 2012 ló pàdánù ìyàwó rẹ̀ tó kọ́kọ́ fẹ́ sọ́wọ́ ikú.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé