Aisha Lawal àti Dejo Tunfulu ṣe ọjọ́ ìbí; Ogogo, Dele Odule, Adebayo Salmai àti Jide Kosokọ gba àmì ẹ̀yẹ kú iṣẹ́!

Oríṣun àwòrán, Aisha Lawal/DEJO2NFULU
Oriṣiriṣi nkan lo ṣẹlẹ lagbo oṣere tiata Yoruba laarin ọsẹ yii, bi awọn kan ṣe n ṣe ọjọ ibi lawọn mii n jẹ igbadun eto "Waa gbayi" ti ileeṣẹ kan to n po ọti ṣeto rẹ.
Lara awọn to ṣe ọjọ ibi lagbo oṣere laarin ọsẹ yii ni agbaọjẹ apanilẹrin Kunle Adetokunbo ti ọpọ mọ si Dejo Tunfulu.
Dejo Tunfulu
Gẹgẹ bii ohunn ti a mọ, wọn bi Dejo ninu oṣu Karun un ọdun 1972.
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Àjọ NYSC kò gbèrò rírán àwọn àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun- Àjọ NYSC
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
- Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Muhammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án tí àwọn èèyàn ń mu
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lori ayelujara atawọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata lo n ki ni mẹsan-mẹwaa layajọ ọjọ ibi rẹ ọhun.
Muyiwa Ademola atawọn agba oṣere mii lo fi ọrọ wuri ati adura ranṣẹ si Dejo lọjọ naa.

Oríṣun àwòrán, Aisha Lawal
Aisha Lawal
Ọpọ awọn ololufẹ Aisha Lawal atawọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo ba yọ ni ayajọ ọjọ ibi rẹ naa to ṣe larin ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan to kọ loju opo Instagram rẹ lọjọ naa lo ti ṣọpe fun laafia to si tun n gbadura fun ẹmi gigun.
Aisha sọ pe "Mo le ma tii de ibi ti mo lero lọkan ṣugbọn mo moore ibi ti mo ti de. Ninu gbogbo nnkan, o yẹ ki a maa dupe."

Oríṣun àwòrán, @Ogogo
Ogogo, Yinka Quadri, Dele Odule, Adebayo Salami ati Prince Jide Kosoko
Laarin ọsẹ yii naa ni ileeṣẹ International Breweries Plc to n po ọti Trophy ṣe ayẹsi fun awọn agbaọjẹ oṣere tiata lori eto wọn kan ti wọn pe ni "Wa a gbayi."
Lara awọn agba oṣẹre naa ni Ogogo, Yinka Quadri, Dele Odule, Adebayo Salami ati Prince Jide Kosoko
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Kò sí ìjà kankan láàrín èmi àti Saheed Osupa - Muri Thunder
- À ń ṣe ara wa ni Bí a bá kọ̀ láti máa lo egbòogi igbó ní Naijiria - Akeredolu
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí 'twitter' tíjọba dá dúró ní Nàijíríà yóò ṣe kan ọ

Oríṣun àwòrán, @Yinka Quadri














