Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti kede rẹ pe aleekun ti ba owo oṣu awọn agunbanirọ to n sin ilẹ baba wọn nipinlẹ Ọyọ lati ẹgbẹrun marun un si ẹgbẹrun mẹẹdogun naira loṣu.
Makinde ṣe ikede naa l'Ọjọbọ lasiko to ṣe abẹwo si ibudo ifinimọlẹ awọn agunbanirọ to n bẹ nilu Isẹyin n'ipinlẹ Ọyọ.
Ikede yii si mu ki idunnu ṣubu lu ayọ fun gbogbo awọn agunbanirọ to wa nibi ipejọpọ naa gẹgẹ bi a ṣe ri i ninu fọnran kan.
- Ẹ leè rán àwọn Àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun, wọ́n kójú òsùwọ̀n - Ọ̀gá àjọ NYSC
- 'Títí ọdún mẹ́wàá gbáko! A o ni kó Àlùbósà lọ sílẹ̀ Ibo, kí la rí gbà nígbà tí ojà Sasha jóná?'
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ tun ṣe ikede naa lori ikanni ikansiraẹni Twitter. O ni: "A ṣe abẹwo si ibudo ifinimọle awọn agunbanirọ to n bẹ nilu Isẹyin ni irọlẹ oni.
Mo fi da awọn agunbanirọ naa loju wi pe a o wa ojutu si awọn ipenija to n koju ibudo naa.

Bakan naa ni mo sọ fun wọn pe a o sun owo oṣu wọn soke lati ẹgbẹrun marun un ti o wa tẹlẹ lọ si ẹgbẹrun mẹẹdogun naira".
Ninu ọrọ ti o sọ lori pataki sisin ilẹ baba ẹni, Makinde ni lasiko ti oun lọ ṣẹ agunbanirọ nilu Port Harcourt ni oun ti ri iṣẹ ti oun si tun ṣe alabapade aya ti oun fẹ.
Eleyii si tun mọ si wi pe oun duro gẹgẹ bi apere awọn anfani to wa ninu ki a in ilẹ baba ẹni.
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari














