NYSC: Àjọ NYSC ní àwọn kò gbèrò rírán àwọn àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun

Oríṣun àwòrán, Nysc
Ajọ agunbanirọ lorilẹ-ede Naijiria ti sọ pe aṣitumọ ni ọrọ oludari agba ajọ naa, Ọgagun Shuaibu Ibrahim ja si bayii.
O ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin laipẹ yii lohun ti awọn kan n sọ kiri pe ajọ NYSC fẹ ko awọn agunbanirọ lọ jagun gẹgẹ bi o ṣe n ja ranyin lori ayelujara bayii.
Ajọ naa ṣalaye ninu atẹjade kan lori ikanni Twitter rẹ pe ajọ naa ko fi igbakankan gbero tabi sọ pe oun yoo ko awọn agunbairọ ls soju ogun,
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
- Aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó mi, mi ò kí ń sá a níta gbangba - Saheed Balogun
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
Wọn ni ohun ti adari agba ajọ naa sọ fun awọn akọroyin ni pe ni ibamu pẹlu ilana abo orilẹede Naijiria, awọn agunbanirọ dabi awọn ọmogun to wa ni ipamọ ni.
O ṣalaye pe nitori ẹkọ wọn ati ọlaju wọn yoo lee mu ki wọn wulo tabi yii po si idanilẹkọ ologun.
Oludari agba ajọ naa si rọ wọn lati gbajumọ afojusun wọn ki wọn si jẹ olootọ si orilẹede Naijiria, ki ẹmi afojusun eto agunbanirọ lee maa gbe ninu gbogbo ọmọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ screenshot
Bakan naa ni wọn ni Ọgagun Ibrahim ko figba kankan sọ pe wọn n pese awọn agunbanirọ silẹ lati lọ jagun.
Ajọ NYSC fi kun un pe nigbagbogbo ni awọn alaṣẹ ajọ naa n sare bi abo ati alaafia yoo ṣe wa fawọn agunbanirọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, NYSC
Ẹ leè rán àwọn Àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun, wọ́n kójú òsùwọ̀n - Ọ̀gá àjọ NYSC
Ọga agba ajọ awọn agunbanirọ ni Naijiria, Ọgagun Shuaibu Ibrahim ti ni awọn agunbanirọ naa wa lara awọn ikọ alaabo Naijiria torinaa wọn lee lọ oju ogun.
Ibrahim sọ ọ̀rọ̀ yii lori eto owurọ kutu ti ileeṣẹ amohunmaworan Channels l'Ọjọbọ nigba to n fesi lori ọrọ to jjade laipẹ pe ki ijọba fagile isinru ilu.
Ọga ajọ naa ni awọn agunbanirọ wa digbi nikalẹ gẹgẹ bi kan lara awọn ikọ alaabo Naijiria torinaa "bi ogun to gbona ba yọju, ọmọwe ni awọn agunbanirọ wa, wọn si lee gba ẹkọ tori lara r naa la n mu wọn la kọja ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Ètò àgùnbánirọ̀ NYSC yóò máa tẹ̀síwájú - Mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àteré ìdárayá
- Ìpayà ní Kano lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ Àjọ NYSC kú lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn Coronavirus
- Wo ìdí tí akẹ́kọ̀ọ́jáde 96 kò fi ní leè ṣe àgùnbánirọ̀ wọn l'Ogun
- Àjọ NECO kéde ọ̀gá àgbà fìdíhẹẹ́ tuntun lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ọ̀gá àgbà àná jáde láyé
- Tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa Fathia Balogun, aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni, mi ò kí ń sá a níta gbangba - Saheed Balogun
"Ẹ lee woye pe laarin ọsẹ mẹta ti wọn n lo nibi eto ilanilọyẹ, wọn maa n ki awọn agunbanirọ naa bi ologun. Ẹ o ri awn agunbanirọ obinrin to n fọn fere ologun ti wọn si n ba awọn onilu ologun lulu".
O ni torinaa bi kii ba ṣe ti iru ẹkọ ti awọn n kọ wọn , nibo lẹ ti le ri iru awọn ọdọ Naijiria yẹn kojọ lati tete kọkọ wọn fun iwulo orilẹede wọn.
- 'Títí ọdún mẹ́wàá gbáko! A o ni kó Àlùbósà lọ sílẹ̀ Ibo, kí la rí gbà nígbà tí ojà Sasha jóná?'
- A tí ń gbé ìgbésẹ́ láti kó àwọn tó ja bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbà ní Ondo- Komisonna Bolaji Salami
- Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ UNILORIN lòpọ̀ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀?
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
Ọgagun Shuaibu ni aabo awọn agunbanirọ jọ awọn loju torinaa ni awọn ṣe gba wọn nimọran lati ma rin kiri lalẹ.
O fi kun un pe agunbanirọ ti ṣe pataki gan lakoko yii paapaa loju ijagbara fun iyapa to n lọ kaakiri lọwọlọwọ ni Naijiria.
















