Akeredolu: Ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ fi òǹtẹ̀ lu igbó lílò ní ẹ̀ka ètò ìlera

Weed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ṣalaye idi to fi ṣe pataki ki ijọba Naijiria fi ontẹ lu egboogi igbo fun lilo ni ẹka eto ilera ati eto ọrọ aje.

Akeredolu lo sọ ọrọ naa lasiko to n dahun awọn ibeere lori eto kan lati ṣami si ayẹyẹ ọgọrun ọjọ rẹ lori alefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo fun saa keji.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, igbo yoo wulo fun Naijiria lati pa owo wọle lati ilẹ okeere.

O ni "ninu iwoye temi, mo gbagbọ pe o yẹ ki a maa lo igbo fun iwosan ni ẹka eto ilera nitori ko si ohun to buru nibẹ."

"Ọpọ awọn eeyan lo n wa igbo kiri loke okun, a si n ṣe ara wa ni ti a ba kọ lati lo egboogi naa lati pa owo wọle."

Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi/ Getty

Aketi ṣalaye pe oun ti rinrinajo lọ si orilẹ-ede Thailand atawọn ilẹ mii, oun si ri bi wọn ṣe n lo egboogi naa fun iwosan, ko si buru ti wọn ba n ṣe irufẹ nnkan bẹẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Gomina ọhun ni "nigba ti a lọ si Thailand fun iwadii nipa bi a ṣe le maa jere lati ara igbo, koda, ọga agba ajọ NDLEA gan tẹle wa lọ, ṣugbọn mi o le ṣo ohun to mu bọ lati ibẹ."

Akeredolu ni igbabọ oun ni pe egboogi naa yoo wulo ti wọn ba n gbin in ni ọna to ba ofin mu.

O ni lootọ ni Naijiria ni isọro awọn to n lo egboogi oloro ni ọna ti ko tọ, ṣugbọn ijọba le wa ọna miran lati maa lo igbo fun iwosan awọn eeyan ati lati maa pa owo wọle.

O pari ọrọ rẹ pe oun atawọn alabaṣiṣẹ oun yoo jiroro lori ọna ti ijọba fi le maa jẹ anfani lori igbo.

Ṣaaju ni ile aṣoju-ṣofin ti kọkọ daba igbo gbigbin ni Naijiria ati bi ijọba apapọ ṣe le lo egboogi naa lati pa owo wọle.

Abadofin ọhun, ti Miriam Onuoha gbe wa siwaju ile naa ti de ipele keji bayii niwaju ile naa.

Lọwọ yii, o lodi si ofin ki eeyan maa gbin tabi ta igbo ni Naijiria.

Ṣugbọn ti abadofin ọhun ba le di ofin, awọn dokita ati ile iwosan yoo lẹtọ lati juwe rẹ fun awọn alaisan gẹgẹ bii oogun, bẹẹ ni awọn ile ti wọn ti n ta oogun yoo lẹtọ lati maa ta a.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....