United African Republic Nigeria: Bí Nàìjíríà ṣe yí orúkọ si 'UAR' tàbí ''United Alkebulan Republic'' yóò ṣe?
![United African Republic Nigeria: "United Africa Republic" [Nigeria] UAR - How 'Nigeria name change to UAR' go be?](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/B66C/production/_118800764_unitedafricanrepublicnigeriaunitedafricarepublic-nigeriauar-how'nigerianamechangetouar'gobe.png.webp)
Oríṣun àwòrán, Presidency
"United Africa Republic" tàbí 'United Alkebulan Republic' [UAR] ni orúkọ tí àwọn ará ìlú gbà nímọ̀ràn láti sọ orúkọ ''Naijiria" orúkọ tó n jẹ́ báyìí. Kíní àwọn nǹkan tó wà nínú àyípàdà orúkọ.
Àyípada orúkọ kìí ṣe nǹkan tuntun fún ọlọ́dani, ilé iṣẹ́ tàbí orílẹ̀-èdè. Ati pé ó kéré tan, ó kéré tán àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gbòmìnira lé ni mọ́kànlélógún wọ́n sì ti yí orúkọ wọn padà.
- Mo bá òkú Blessing tí wọ́n so ọwọ́ ẹ̀ sẹ́yìn pẹ̀lú ìwé pélébé tí wọ́n kọ pé ... - Òbí akẹ́kọ̀ọ́ Unilorin tí wọ́n bálòpọ̀ dójú ikú
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- A tí ń gbé ìgbésẹ́ láti kó àwọn tó ja bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbà ní Ondo- Komisonna Bolaji Salami
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND
- Aṣọ ìkọ̀kọ̀ ni ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó mi, mi ò kí ń sá a níta gbangba - Saheed Balogun
Nínú ọ̀rọ̀ yìí ọmọ Nàìjíríà kan Adeleye Jokotoye tó pè fún orúkọ Nàìjíríà tuntun tó gbé sílẹ̀ fún ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó lórí àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ òfin nílé ìgbìmọ̀ asòfin Nàìjíríà
Ìjọba Orílẹ̀-èdè sọ pé ààrẹ Muhammadu Buhari kò lọ́wọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ náà
Jokotoye sàlàyé pé ìdí tí ó fi fẹ́ kí orúkọ náà maa jẹ́ United African Republic ni pé oníruurú èdè ló wà ní nàìjíríà tó sì yẹ kí wam kórajọpọ̀
![United African Republic Nigeria: "United Africa Republic" [Nigeria] UAR - How 'Nigeria name change to UAR' go be?](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/179BC/production/_118800769_unitedafricanrepublicnigeriaunitedafricarepublic-nigeriauar-how'nigerianamechangetouar'gobe.jpg.webp)
United Africa Republic tí wọ́n yí orúkọ Nàìjíríà padà sí- Kíní àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀?
Ní Nàìjíríà àwọn ilé igbìmọ̀ àṣòfin nìkàn ló ni agbara láti yí orúkọ orílẹ̀-èdè pada, yálà láti yí òfin pàdà tàbí yí orúkọ orílẹ̀-èdè kan padà.
" Nítórí nàá tí ìwé ẹ̀bẹ̀ náà bá yí bírí wọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ yóò gbeyẹ̀wò láti jíròrò lé lórí láti kọ́ja ipò abádòfin" èyí ni ọ̀rs ti agbẹjọ́rò Sogbeye Eli sọ.
Yóò gba ipele kíkà àkọ́kọ́, lẹ́yìn èyí ni wan yóò pe ìpàdé ìtagbangba fún gbogbo ará ìlú láti wá sọ̀rọ̀ le lórí, lẹ́yìn èyí ni yóò wa gba ipele kẹtá láti di òfin ti ààrẹ bá buwọ lùú.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó lórí àgbéyẹ́wò òfin nílé ìgbìmọ̀ àṣòfin Nàìjíríà ń ṣe àtúntò òfin ọdún 1999 ti wọ́n sì tí kédé fún àwọn ọmọ Nàìjíríà jákèjádò ẹkùn mẹ́fẹ̀fẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìpàdé ìtàgbangba ttí ẹkun ìwọ̀-òòrùn -Guusu wáyé ni ìlú Ikeja ni ìpínlẹ̀ Eko ní ọjakini àti ìkèjì osun kẹfa ọdún yìí, ibẹ̀ sí ni wan ti fi ìdí rl múlẹ̀ pé Jokotoye, ónímọ̀ nípà ètò owó-orí tí gbé àbá náà kalẹ̀ láti yí orúkọ Nàìjíria
![United African Republic Nigeria: "United Africa Republic" [Nigeria] UAR - How 'Nigeria name change to UAR' go be?](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/12B9C/production/_118800767_unitedafricanrepublicnigeriaunitedafricarepublic-nigeriauar-how'nigerianamechangetouar'gobe.png.webp)
Oríṣun àwòrán, Presidency
Kíní àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ nípà àyípàdà orúkọ náà tó bá wáyé?

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Odas

Oríṣun àwòrán, Odas

Oríṣun àwòrán, Odas

Oríṣun àwòrán, Odas

Oríṣun àwòrán, Odas

Oríṣun àwòrán, Odas















