Animal market Ayobo, Ipaja, Ikorodu, Mangoro: Ìjọba ti gbé odò ẹran àti ọjà mẹwàá tìpa l'Eko

Odo ẹran

Oríṣun àwòrán, Others

Kọmiṣọnna eto ọgbin, Arabinrin Abisola Olusanya ṣalaye pe ijọba gbe igbesẹ lati ti awọn odo ẹran ati ọja ti wọn ti n ta ẹran tipa nitori o lodi sofin ipinlẹ Eko.

Awọn agbegbe bii Ayobo, Ipaja, Oko Filling, Ikorodu, Odogunyan road, Mangoro to fi mọ opopona mọrosẹ to lọ si Abeokuta ni wọn ti ti awọn odo ẹran naa pa.

Kọmiṣọnna Olusanya ni igbesẹ yii wa lara eto imọtoto ati atunṣe ti ijọba n ṣe lori ati maa jẹ ki awọn araalu ri ẹran to dara jẹ.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

O ṣalaye pe ẹran agbo mọkanlelogun, orukọ mẹtala ati ẹran maalu ti wọn ti pa eyi ti wọn n ta.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Arabinrin Olusanya ni awọn ti fi ẹran tawọn gba tọrọ sile awọn ọmọ alainiya at'awọn ajọ mii to n ṣeranwọ fun araalu.

Bakan naa lo sọ pe awọn yoo ta awọn ẹran agbo ati orukọ tawọn gba nile ẹjọ alagbeeka awọn ẹṣọ agbofinro lori ọrọ ayika.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Kọmiṣọnna ni gbogbo awọn gbogbo awọn alapata ti ọwọ tẹ ni yoo foju ba ile ẹjọ.