Dejo Tunfulu: Yomi Fabiyi ní olóògbé kò dúró gba owó iṣẹ́ tí wọ́n jọ ṣe kẹ́yìn nítorí àisàn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @dejomania
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Yomi Fabiyi ti sọrọ lori iṣẹ ti oun ati akẹgbẹ rẹ to di oloogbe, Dejo Tunfulu ṣe kẹyin, ki ọlọjọ to de.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Yomi Fabiyi sọ pe oju Dejo ko gun rege, o si jọ ti ẹni ilera rẹ ko ṣe dede lọjọ naa lọhun.
Gẹgẹ bi oun to sọ, inu oṣu Kinni, ọdun 2022 yii ni oun pe Dejọ si iṣẹ kan, amọ asiko to yẹ ki wọn ya ipa tirẹ ninu ere naa ni oun ṣakiyesi pe ara rẹ ko da.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wèrè ọlọ́mọ ní Dejo Tunfulu, ọmọ mẹ́rin ní ìyá wa dà sílẹ̀ fún, tó sì bá ọkọ míì lọ - Ọmọ olóògbé
- Wo gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méjọ tó ti kú saájú Dejo Tunfulu
- Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa Dejo Tunfulu tó jáde láyé
- Mo ti gba ìdúnkookò ikú tórí mo tako ṣíṣí bodè Lekki padà - Mr Macaroni
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- Ọ̀rọ̀ Amaechi àti El-Rufai fihàn pé ìjọba lọ́wọ́ nínú ìgbésùnmọ̀mí – PDP
- Irọ́ ní Atiku, Saraki, Tambuwal àtàwọn yókù ń pa pé àwọn ọ̀dọ́ ló dá N40m owó fọ́ọ́mù ìdíje sípò ààrẹ fún àwọn - Obasanjo
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
- Ìgbésẹ̀ yíyan Olówu di wàhálà, àwọn ìdílé oyè wọ́ ara wọn relé ẹjọ́
- Ọmọ ìjọ kú sí ìpàgọ́ Bíbélì, pásítọ̀ sìnkú rẹ̀ láì sọ fún ẹbí rẹ̀
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
O ni "Mo mọ pe ara rẹ ko da nitori o wa sibi ti mo ti n ya ere kan ninu oṣu Kinni, oju rẹ si jọ ti ẹni to n ṣaisan."
"Mo wa beere lọwọ rẹ ohun to de, o ni ara oun ko da amọ oun ti n gbadun."
"Nigba ti akoko to lati ya ipa tirẹ ninu ere naa, mo beere lọwọ rẹ pe ẹgbọn ki lo ṣe yin?
O si dahun pe ara oun ko da. A si tete ya ipa tirẹ ninu ere naa nitori awọn ọmọ ita n yọ wa lẹnu nibi ti a ti n ya ere ọhun."
Yomi ni oun ko ri aye beere Dejo nipa ohun gan to n yọ oloogbe naa lẹnu ni pato, nitori pe o tete fi agbegbe ti wọn ti n ya ere naa silẹ.
Koda, o ni ko duro gba owo isẹ rẹ lọjọ naa lọhun.
Fabiyi tẹsiwaju pe "Ko duro gba owo iṣẹ rẹ lọjọ ti a n sọ yii, mo wa pe lori ago pe ẹgbọn, ẹ ko tilẹ duro gba owo yin?
O wa ni ki n fi owo naa ranṣẹ si apo ifowopamọ banki oun."
Nibo ni Dejo dakẹ si?
Yomi Fabiyi ṣalaye fun BBC pe ile iwosan gbogbogbo to wa ni Ikorodu, niluu Eko ni oloogbe naa dakẹ si.
Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko le sọ ni pato irufẹ aisan to mu ẹmi rẹ lọ.
O ni bi oun ṣe gbọ iroyin nipa iku rẹ ni oun gbera lọ sile iwosan ọhun, ti oun si le fidi rẹ mulẹ ile iwosan naa lo dakẹ si.
Irufẹ aisan wo lo mu ẹmi Dejọ lọ?
Bo tilẹ jẹ pe Yomi Fabiyi sọ pe oun ati oloogbe naa ko ri aye lati sọrọ lori irufẹ aisan to n ba finra ni pato, awọn iroyin kan sọ pe arun iba 'typhoid' lo ṣekupa.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ana ode yii ni awọn mọlẹbi rẹ gbe digbadigba lọ sile iwosan ijọba to wa ni Ikorodu lẹyin ti wọn ṣakiyesi pe ẹjẹ ti n gbẹ lara rẹ.
Iroyin naa ni ibi ti wọn ti n fa ẹjẹ si lara lo ti dakẹ.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu to n bọ lo yẹ ki Dejo pe ẹni aadọta ọdun loke eepẹ.
Oni yii naa ni wọn yoo sin oku rẹ ni ilana ẹsin Musulumi niluu Ikorodu.



















