Lekki Toll Gate: Wọ́n ti fi iṣẹ́ ikú ránṣẹ́ sí Mr macaroni torí ó tako ṣíṣí ẹnu bodè Lekki padà

Oríṣun àwòrán, mrmacaroni1/Instagram
Gbajumọ adẹrinposonu ori ayelujara, Debo Adedayo, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Macaroni ti kede pe ẹmi oun ko de, oun si wa ninu ewu.
Macaroni, ẹni to fi ikede yii soju opo Twitter rẹ, @mrmacaroni lọjọbọ salaye pe awọn eeyan kan ti n dunkoo iku mọ oun, ti wọn si n fi atẹjisẹ iku ransẹ.
O ni idunkooko naa ko sẹyin bi oun se tako igbesẹ gbigba owo bode pada lẹnu iloro Lekki si Ajah.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa Dejo Tunfulu tó jáde láyé
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- Ọ̀rọ̀ Amaechi àti El-Rufai fihàn pé ìjọba lọ́wọ́ nínú ìgbésùnmọ̀mí – PDP
- Irọ́ ní Atiku, Saraki, Tambuwal àtàwọn yókù ń pa pé àwọn ọ̀dọ́ ló dá N40m owó fọ́ọ́mù ìdíje sípò ààrẹ fún àwọn - Obasanjo
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
- Ìgbésẹ̀ yíyan Olówu di wàhálà, àwọn ìdílé oyè wọ́ ara wọn relé ẹjọ́
- Ọmọ ìjọ kú sí ìpàgọ́ Bíbélì, pásítọ̀ sìnkú rẹ̀ láì sọ fún ẹbí rẹ̀
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
Macaroni, ẹni to wa lara awọn ọdọ to lewaju iwọde EndSARS losu kẹwa ọdun 2020, lo ti kede saaju lati tako igbesẹ sisi ẹnu iloro naa pada lọjọ Kinni osu Kẹrin ọdun 2022.
Adẹrinposonu ori ayelujara naa ni lẹyin idajọ ododo fawọn eeyan to fori sọta isekupani ọlọgọọrọ ni Lekki, awọn ko ni fara mọ ohunkohun miran lẹyin rẹ.
Bakan naa lo tun doju kọ ẹni kan to n beere pe ki lo de to fi n tako igbesẹ sisi ẹnu iloro naa.
Ọkan lara awọn eeyan to n lo oju opo Twitter, to pe orukọ ara rẹ ni Ọmọọba Tiamiyu wa leri leka si alawada ori ayelujara naa pe oun yoo pa.
Tiamiyu ni ti Macaroni ko ba jawọ ninu atako to n se si igbesẹ sisi ẹnu iloro Lekki pada, yoo fi iku se ifa jẹ.
"Ọkunrin to pe ara rẹ ni Macaroni yii lo seese ko padanu ẹmi rẹ laipe ọjọ nitori iwa omugọ rẹ.
Ko ni ọpọlọ kankan, ko nifẹ ilu rẹ, ọmọ ale abi ki ni wahala tiẹ lori ọrọ sisi ẹnu bode Lekki pada?
Mo gbadura pe ki ọwọ ba lọla nigba ti wn ba si ẹnu pada, maa pa ti mo ba foju mi kan." Tiamiyu lo sọ bẹẹ.
Idunkooko iku yii si lo mu ki Macaroni gbe ọrọ naa soju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki ni iha ti Mr Macaroni kọ si idunkooko iku naa?
Nigba to n fesi lori idunkooko iku ti wọn fi ransẹ si naa, Macaroni ni "Ọkan lara awọn idunkooko iku ti mo maa n gba loore koore ree.
Ileesẹ ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Eko...mo nifẹ yin, gẹgẹ bi mo se lero pe ẹ nifẹ emi naa."
Isẹlẹ yii si ni awọn ọmọ Naijiria ti n gba yẹwo lori ayelujara, to si n mu ariyanjiyan lọwọ pẹlu.

















