Favour Okumazor.: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ogun mú pásítọ̀ méjì tó sin òkú ọmọ ìjọ láì sọ fún ẹbí rẹ̀

Ile ijọsin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti ṣafihan pasitọ kan, ati oluranlọwọ rẹ, ti wọn fi ẹsun kan pe o sin oku ọmọ ijọ rẹ kan lai sọ fun awọn ẹbi oloogbe.

Iroyin sọ pe lọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, ni Pasitọ Chidi Ejiogu ti ile ijọsin Life Buiders Network, Mowe, ati oluranlọwọ rẹ, Paul Zakari, ko awọn ọmọ ijọ wọn lọ fun ipagọ ẹkọ Bibeli ni abule Oyan, nipinlẹ Ogun.

Lara awọn ọmọ ijọ naa ni arabinrin ẹni ogun ọdun kan, ti wọn pe orukọ rẹ ni Favour Okumazor.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ iroyin Vanguard jabọ pe ipagọ Bibeli ọhun n lọ lọwọ, ni ajeji aisan kan deede kọlu gbogbo awọn olukopa nibẹ.

Favour la gbọ pe o n bì, to si tun n ṣe igbọnsẹ leralera ni ọjọ ti aisan naa bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Nigba ti yoo si fi di oru ọjọ naa, o ti ku.

Nkan to wa jẹ iyalẹnu ni pe kiakia ni wọn sin oku rẹ si abule naa, lai sọ fun ẹbi rẹ pe ọmọ wọn ti ku.

Pasitọ Chidi sọ pe ikọlu lati inu ijọba okunkun ni nkan to ṣẹlẹ si awọn:

Nigba to ṣafihan awọn afurasi naa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun to wa nilu Abeokuta, kọmisanna ọlọpaa, Lanre Bankole, sọ pe ẹnikan ti ori ko yọ lara awọn ọmọ ijọ naa lo sa kuro ni abule Oyan, to si sọ nnkan to ṣẹlẹ fun awọn ọlọpaa.

Oun naa lo si ṣe atọna bi ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ awọn afurasi mejeeji.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Pasitọ Chidi sọ pe ikọlu lati inu ijọba okunkun ni nkan to ṣẹlẹ si awọn.

O ni lootọ ni oun ṣakiyesi pe aisan kọlu gbogbo awọn ti oun ko lọ fun iṣẹ ihinrere, amọ ireti oun ni pe oun le fi igbagbọ wo wọn san, dipo ko gbe wọn lọ sileewosan.

O ṣalaye pe ọjọ kẹta ti ipagọ bẹrẹ ni iṣẹlẹ naa waye.

Ati pe oun kabamọ pe oun sin oku ọmọbinrin naa lai sọ fun awọn ẹbi rẹ.

Ipagọ adura ati ẹkọ Bibeli kii ṣe nkan to jẹ ajeji laarin awọn ẹlẹsin Kristiẹni, koda to fi mọ awọn ijọ nla to l'orukọ.

Ọpọ wọn si lo ma n sẹ ipagọ naa ni awọn ibi ti wọn ya sọtọ, to le jẹ ninu ile ijọsin wọn tabi nibomiran.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí