US embassy visa appointment: Wo bí o ṣe le jànfàání ìwé ìrìnnà sí US láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Iwe irinna ilẹ America ti wọn buwọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ aṣoju America ni Naijiria, ẹka ti Abuja, ti sọ pe oun ti bẹrẹ eto ṣiṣe iwe irinna fun awọn arinrinajo kan lai ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun wọn.

Ọjọru, ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2022 ni eto tuntun naa bẹrẹ.

Ninu ikede ti ileeṣẹ naa fi si ori ayelujara Twitter rẹ lo ti sọ pe eto naa wa fun awọn to ti gba iwe irinna ri, ṣugbọn to fẹ ẹ tun ontẹ gba.

Ati pe o wa fun awọn ti ko ni erongba lati fi America ṣe ibugbe wọn.

Iwe irinna ọhun gbọdọ jẹ́ B1/B2, F, M, J (fun eto ẹkọ) tabi H, L, C1/D

Awọn wo lo ni anfaani si eto tuntun yii?

  • Ẹni to ti gba iwe irinna ri, amọ ti ko ti i ju oṣu mẹrinlelogun ti ọjọ lọ lori rẹ, tabi eyi ti ọjọ yoo lọ lori rẹ laarin oṣu mẹta si asiko ti wọn kọwe beere fun ontẹ tuntun
  • To ba jẹ pe orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti gba iwe irinna ti tẹlẹ
  • Iwe irinna to fun ni ni anfaani lati wọ America ni ilọpo igba
  • Iru iwe irinna ti o ni lọwọ tẹlẹ naa lo fẹ ẹ pada gba
  • Ẹni to fẹ ẹ gba iwe irinna naa ko ti i hu iwa ọdaran kankan ri tabi lọ si ẹwọn nilẹ America (koda, ko jẹ pe wọn ti ri idariji gba)
  • Ẹni to fẹ ẹ gba iwe irinna ko ṣiṣẹ ri ni America lai gba iwe aṣẹ, tabi lo ju asiko to yẹ ko lo ni orilẹ-ede naa

Bakan naa ni ileeṣẹ aṣoju naa tun sọ pe awọn amuyẹ obi to fẹ ẹ gba iwe irinna, ko le ṣiṣẹ fun ọmọ rẹ.

Ọmọ naa gbọdọ koju osunwọn ni aye ara rẹ.

Awọn nkan ti o gbọdọ ṣe ko to o to kọwe fun iwe irinna lai ṣe ifọrọwanilẹnuwo

O ni lati lọ si ori ayelujara ileeṣẹ aṣoju America ni Naijiria lati fi orukọ silẹ, ko si yan ọjọ ti o fẹ ṣe agbeyẹwo awọn iwe ẹri rẹ.

Wa a fi pasipọọti rẹ, iwe DS-160 rẹ, fọto tuntun ati iwe ẹri pe o ti san owo to yẹ ranṣẹ si ibi ti wọn ba yan fun ọ

O ko ni i ni anfaani si pasipọọti rẹ titi wọn o fi pari eto iwe irinna rẹ, eyi to le to oṣu meji gbako.

Bakan naa ni ikede naa sọ pe owo to o san ko ti i kuro ni iye to wa tẹlẹ, ọgọjọ Dọla ati aadọwa Dọla fun awọn ipele to wa.

Ṣugbọn ṣa, wọn ni awọn yoo kọwe si ẹni ti ọrọ rẹ ba pada nilo pe ko ṣe ifọrọwanilẹnu, lati yan ọjọ̀ ti yoo yọju sileeṣẹ ajọ naa.

Oṣu Keji ni iru eto yii bẹrẹ ni ẹka ileeṣẹ aṣoju America to wa nipinlẹ Eko.