Kí ló pa dókítà àjọ FIFA tó kú níbí ìdíje Ghana vs Nigeria ní Abuja? Àjọ NFF sọ̀rọ̀

Doita Joseph Kabungo

Oríṣun àwòrán, Nkweto Tembwe

Ajọ bọọlu ni Naijiria, NFF ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori iku oṣiṣẹ eto ilera kan, Dokita Joseph Kabungo, to ku lẹyin ifẹsẹwọnsẹ Ghana ati Naijiria nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.

Ṣaaju iku rẹ, Dokita Kabungo to wa lati Zambia, wa lara awọn oṣiṣẹ ilera to ṣe ayẹwo fun awọn agbabọọlu lati mọ boya wọn lo oogun oloro.

Atẹjade kan lati ẹka iroyin ajọ NFF sọ pe lootọ ni iku dokita naa jẹ ẹdun ọkan, ṣugbọn o ṣe pataki ki oun sọrọ lori nkan to fa iku rẹ.

Ṣaaju ni iroyin ti n tàn kiri pe lasiko ti awọn ero iworan to jẹ ololufẹ Super Eagles ti Naijiria yawọ ori papa lati fẹhonu han nitori ifidirẹmi ẹgbẹ agbabọọ̀lu naa ni wọn lu oloogbe Kabungo pa.

Awọn ero iworan naa wọ ori papa, ti wọn si bẹrẹ si ni ju oriṣiriṣi nkan mọ awọn agbabọọlu Super Eagles nitori wọn fi idi rẹmi.

NFF ni dokita ajọ naa ti FIFA yan lati wa nibi ifẹsẹwọnsẹ naa, Dokita Onimisi Ozi Salami, sọ pe awọn kan lo ri oloogbe Kabungo nibi to ti n pọkaka iku, nitori ko le mi daadaa.

Eyi lo waye nitosi yara ti ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede ghana ti n wọ aṣọ.

"Awọn to ri oloogbe sọ nkan to n ṣẹlẹ fun mi. Mo si paṣẹ pe ki wọn o tete ma a gbe lọ sileewosan.

"Ṣugbọn bi wọn ṣe n de ẹnu ọna ileewosan lo kú."

Dokita Ozi Salami sọ fun awọn aawọn alaṣẹ ajọ NFF pe lasiko ti Dokita Kabungo fẹ ẹ lọ pe awọn agbabọọlu orilẹ-ede Ghana lati wa ṣe ayẹwo ni iṣẹlẹ naa waye.

"Emi naa fẹ ẹ lọ pe awọn agbabọọlu Naijiria, ni ẹni to jẹ oludari eto gbogbo, Kabore Hubert Bosilong, lati South Africa, pe akiyesi mi si bi Dokita Kabungo ko ṣe le mí daadaa mọ lojiji."

O ni iṣẹlẹ naa ṣoju oṣiṣẹ alaabo ajọ FIFA, Dixon Adol Okello lati Uganda.

NFF sọ pe aisan ọkan ti wọn n pe ni 'heart attack' tabi 'cardiac arrest' lo pa oloogbe.

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Dokita Joseph Kabungo to d'oloogbe

Ọmọ orilẹ-ede Zambia ni Dokita Kabungo.

Gbajumọ si ni pẹlu nitori pe gbogbo idije bọọlu ni orilẹ-ede Zambia lo ti ma n ṣiṣẹ gẹgẹ bi eleto ilera.

Aarẹ ajọ bọọlu ni Zambia, Andrew Kamanga, ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ọkan pataki ni lagbo bọọlu orilẹ-ede naa, paapaa bo sẹ wa lara ikọ to gba ife idije AFCON lọdun 2012.