World Cup Qualifier: Àwọn olùwòran bá pápá ìṣeré jẹ́ lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ Nàìjíríà àti Ghana

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ọ̀rọ̀ di bó ò lọ, ko yà fún mi lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fi ìbínú hàn ní pápá ìṣerẹ́ Moshood Abiola lẹ́yìn tí ìrètí láti kópa níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ dòfo.
Bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Black Star tí orílẹ̀ èdè Ghana ṣe yọwọ́ kílàńkó Super Eagles Nàìjíríà kúrò láwo láti lè kópa níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wáyé lálẹ̀ àná, àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí àbájáde rẹ̀ kò tẹ́ lọ́rùn yabo orí pápá náà tí wọ́n sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́.
Ní àná ni Nàìjíríà àti Ghana gbá abala kejì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ní pápá ìṣeré Moshood Abiola, Abuja tó sì parí pẹ̀lú ọ̀mì góòlù kọ̀ọ̀kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- A bá dáàbò bó ẹ̀mí aráàlú tí ìgbésẹ́ ṣíṣe ẹ̀rọ ayàwòrán síbùdókọ̀ rélùwéè kò bá pẹ́ ni - Amaechi
- Osinbajo ṣe àbẹ̀wò síbi ìkọ̀lù ọkọ̀ rélùwè ní Kaduna, ó ní kí ọmọ Naijiria ṣe ọkàn gírí
- Ghana sọ ìrètí Naijiria láti kópa ní World Cup 2022 di òfo pẹ̀lú 1-1
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Ẹ̀mí 15 bọ́ ní Abeokuta àti Sagamu bí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣe ń ràn kiri l‘Ogun
- Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó gbé Abba Kyari lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abuja
- Wo bí òògùn lílò àtàwọn nǹkan mìí ṣe le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́
- Malami ń forí ilé ẹjọ́ gba ara wọn lórí òfin ètò ìdìbò - Falana
- Bàbá ẹni ọdún 72 di èrò ẹ̀wọ̀n ní Ilorin nítorí ayédèrú ìwé ìrìnnà ọkọ̀
Ní abala àkọ́kọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yìí tí wọ́n kọ́kọ́ gbá ní pápá ìṣeré Baba Yara ní Kumasi, Ghana èyí tó parí láìsí góòlù kankan.
Èyí ló mú kí Ghana pegede láti kópa níbi ìdíje ife àgbáyé tí yóò wáyé ní orílẹ̀ èdè Qatar nínú oṣù kọkànlá nítorí òfin tó wà wí pé góòlù àlejò gbéwọ̀n ju tí onílé lọ.

Oríṣun àwòrán, NFF
Ṣaájú ni ìjọba Nàìjíríà ti kéde fífún àwọn ènìyàn ní tíkẹ́ẹ̀tì ọ̀fẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún fún àwọn ènìyàn láti wòran ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ náà, tí èyí sì mú kí pápá ìṣeré tó gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta ènìyàn kún fọ́fọ́.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ dí pẹ̀ ẹ́ túká nígbà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ìkọlù sí àwọn agbágbọ́ọ̀lù Ghana níbi tí wọ́n ti ń yọ̀ pé àwọn pegedé pẹ̀lú jíju omi inú ọ̀rá lù wọ́n.
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ghana náà rí bi kúrò ni wọ́n tún ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́ ní pápá ìṣeré náà èyí tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe láìpẹ́ yìí pẹ̀lú owó ribiribi lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti pápá ìṣeré náà ti wà ní bíbájẹ́.
Gbogbo ìgbìyànjú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti lé àwọn ènìyàn tí inú ń bí náà já sí pàbó pẹ̀lú gbogbo tajútajú tí wọ́n fọ́n dà sí wọn.

Tíkẹ́ẹ̀tì 20,000, ọkọ̀ ọ̀fẹ́ wà fún yín láti fi wòran bọ́ọ̀lù Ghana àti Nàíjíríà lọ́fẹ̀ẹ́ - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Super Eagles Twitter
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ileesẹ to wa fun ere idaraya lorilẹede Naijiria ati ajọ elere bọọlu lorilẹede yii ti gba tikẹẹti iwọle si gbọngan ere idaraya bii ẹgbẹrun lọna ogun.
Tikẹẹti naa ni wọn yoo pin fun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ woran ere bọọlu lọfẹ eyi ti yoo waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ati Ghana lonii.
Igbesẹ naa nileesẹ mejeeji se lati se koriya fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ wa lasiko ifẹsẹwọnsẹ rẹ keji pẹlu akẹẹgbẹ wọn, Black Stars ti orilẹede Ghana.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agbébọn kọlu rélùwéè Kaduna sí Abuja, pa ọ̀pọ̀ èèyàn, jí àwọn míì gbé lọ
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
- Bàbá ẹni ọdún 72 di èrò ẹ̀wọ̀n ní Ilorin nítorí ayédèrú ìwé ìrìnnà ọkọ̀
- Ajá pa ọmọ olówó rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan tí wọn rà á
- Tọkọtaya kó sí gbaga ọlọ́pàá f'ẹ́sùn jíjí ọmọ ọjọ́ mẹ́fà gbé
- Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn
- Agbébọn ṣé ikọlù sí pápákọ̀ òfurufú Kaduna, èèyàn kàn kú níbẹ
- Ọkùnrin kan fípa bá obìnrin tó sùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ lòpọ̀! Wo bí gbẹgẹdẹ ṣe gbiná
- Olùdásílẹ̀ ìjọ méjì di afurasí tó pa ọmọ ìjọ lásìkò ìsìn, wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá
Ifẹsẹwọnsẹ yii ni ikeji laarin ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji nitori ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti waye ni ọsẹ to kọja ni orilẹede Ghana.
Ifigagbaga naa ni ẹgbẹ agbabọọlu fi n kopa lati mọ ẹgbẹ agbọọlu to pegede, ti yoo lọ soju ilẹ Afirika ninu idije fun ife ẹyẹ agbaye.
Wayi o, Amugbalẹgbẹ feto iroyin fun aarẹ Muhammadu Buhari, Bashir Ahmad, ti kede loju opo Twitter rẹ pe awọn ti pese ọkọ ọfẹ fawọn ololufẹ ere bọọlu ti yoo lọ woran ifẹfẹwọnsẹ naa.
Papa isere idaraya MKO Abiola to wa nilu Abuja ni ere bọọlu naa yoo ti maa waye.
Ahmad ni awọn tikẹẹti ọfẹ naa si ti wa ni awọn ibudokọ gbogbo fawọn eeyan to ba nifẹ lati gba wọn.

Oríṣun àwòrán, GFA
Aago kan ọsan ni awọn osisẹ yoo pari isẹ lonii:
Bakan naa ni ijọba Naijiria ti kede pe aago kan ọsan ni ki wọn ti ilẹkun awọn ileesẹ ijjọba pa lonii, lọna ati fun awọn osisẹ ijọba ni anfaani lati lọ woran ifẹsẹwọnsẹ naa.
Atẹjade kan to wa lati ọọfisi Olori osisẹ ọba lorilẹede yii lo sisọ loju ikede naa lna ati se koriya fun ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ wa, Super Eagles.
Bẹẹ ba gbagbe, ọmi ni ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji gba lasiko ti wọn koju ara wọn nilu Kumasi lọjọ Ẹti to kọja.
Orilẹede to ba si bori ninu ifẹsẹwọnsẹ toni ni yoo lọ soju ilẹ Afirika nibi idije fun ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lọdun yii lorilẹede Quatar.





















