2022 Electoral Act: Malami ń forí ilé ẹjọ́ gba ara wọn lórí òfin ètò ìdìbò

Malami àti Falana

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Àkọlé àwòrán, Malami àti Falana

Gbajúgbajà agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Femi Falana ti fẹ̀sùn kan agbẹjọ́rò àgbà àti mínísítà fétò ìdájọ́, Abubakar Malami.

Falana ni Malami lo àwọn ilé ẹjọ́ gíga ìjọba orílẹ̀ èdè yìí láti máa gbé ìdájọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kalẹ̀ lórí ẹsẹ̀ kejìlá abala kẹrìnlélọ́gọ́rin, ìwé òfin ètò ìdìbò ọdún 2022.

Falana ní Malami ń ṣe bí ẹni pé òun kò mọ̀ pé ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja ti ṣaájú gbé ìdájọ́ kan kalẹ̀ wí pé Malami tàbí ẹnìkankan kò ní ẹ̀tọ́ láti tọwọ́bọ ìwé òfin náà lójú tàbí mú àyípadà òfin náà.

Ṣùgbọ́n Malami fẹ́ ṣe àmúṣẹ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Umuahia tó ní kí wọ́n pa abala náà rẹ̀ nínú ìwé òfin ìdìbò.

Falana ní Malami kò le máa mú èyí tó bá wù ú láti tẹ̀lé nínú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ àti pé ó mọ̀-ọ́n-mọ̀ ń jẹ́ kí àwọn ilé ẹjọ́ náà gbé ìdájọ́ tó tako ra kalẹ̀.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Umuahia, ìpínlẹ̀ Abia lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù yìí ní ẹsẹ̀ kejìlá abala kẹrìnlélọ́gọ́rin, ìwé òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 kò tọ̀nà kí wọ́n paarẹ̀ nínú ìwé òfin náà.

Òfin tuntun náà ní ó ti di èèwọ̀ fún ẹni tí wọ́n bá yàn sípò òṣèlú láti dìbò níbi àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí láti gbégbá ètò ìdìbò láì tíì kọ̀wé fi ipò tó wà tẹ́lẹ̀ sílẹ̀.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Evelyn Anyadike ní òfin abala náà kò bá òfin mu àtí pé kò tọ̀nà tó sì rọ Malami láti pa abala náà rẹ́ nínú ìwé òfin náà.

Anyadike ní abala yìí tako ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí tó fi àyè gba àwọn tó bá dipò òṣèlú mú tó ń gbèrò láti gbégbá ìbò láti kọ̀wé fipò sílẹ̀ ní tó bá ku ọgbọ̀n ọjọ́ sí ọjọ́ ìdìbò.

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ Abuja àti Oyo ti ṣaájú gbé ìdájọ́ ọ̀tọ̀ kalẹ̀:

Falana ni ìgbà àkọ́kọ́ rèé nínú ìtàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè yìí yóò máa da orí ilé ẹjọ́ lu ara wọn láti rí ìdájọ́ tó tẹ́ ẹ lọ́rùn gbà.

Ó ní ó pọn dandan kí èyí wá sópin pàápàá bí ètò ìdìbò gbogbogboò ṣe ń bọ̀ lọ́nà.

Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn náà ní ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti ni Ààrẹ Buhari, Malami àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kò gbọdọ̀ yí òfin náà padà.

Bákan náà ló ni ilé ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ Oyo kò tilẹ̀ dá ẹjọ́ le lórí pẹ̀lú ẹ̀sùn pé ẹjọ́ náà kò rí ẹsẹ̀ walẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló fẹ̀sùn kan Malami pé kò fi gbogbo ìdájọ́ yìí tó ilé ẹjọ́ ìlú Umuahia létí kó tó gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ àti pé àlùwàlẹ́ ológbò, ọgbọ́n àti kó ẹran jẹ ni.

Ó ní nítorí pé Malami fẹ́ díje dupò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kebbi lọ́dún tó ń bọ̀ ló ṣe fẹ́ pa òfin náà rẹ́.

Falana ní bí Malami bá fi le pa abala òfin náà rẹ́, ó túmọ̀ sí wí pé yóò kojú ẹ̀sùn kíkọtí àti yíyí àṣẹ ilé ẹjọ́ padà.

Àkọlé fídíò, 'Tóo bá lè bá mi jà, ìwọ wá!' Ademodi Maria tó lu ọmọdékùnrin mìí lálùbami rèé

Malami jiyàn gbogbo ẹ̀sùn Falana

Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kàn sí Mínísítà fétò ìdájọ́, Malami ní gbogbo ìgbésẹ̀ tí òun bá gbé ló wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin.

Nínú àtẹ̀jáde látọwọ́ agbẹnusọ rẹ̀, Umar Gwandu ní Malami kò ní jẹ́ tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti má ṣe tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìròyìn tí kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit