Kemi Adeosun: Ojoojúmọ́ ni mo fi sunkún fóṣù mẹ́ta lórí ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀

Kemi Adeosun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Kemi Adeosun

Àgbàlagbà tó ń sáré nínú ẹ̀gún, bí kò bá lé nǹkan dájúdájú nǹkan ń le nitori ọkunrin to n sọrọ, to n laagun, akọ kun lo n sun.

Mínísítà tẹ́lẹ̀rí fétò ìsúná fún orílẹ̀ èdè yìí, Kemi Adeosun ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ lórí ohun tí ojú rẹ̀ rí nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án wí pé ó ń lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀.

Adeosun ní ojoojúmọ̀ ni òun fi ń wa ẹkún mu fún oṣù mẹ́ta láì ṣe iṣẹ́ kankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adeosun tó sọ̀rọ̀ níbi ètò àpèrò àwọn obìnrin èyí tó wáyé nílẹ̀ United Kingdom tẹ̀síwájú pé àkókò náà dàbí ìgbà tí òun wà nínú kòtò gìrìwò kan.

Akoko to le julọ ninu igba aye mi ni akoko ẹsun gbigba ayederu iwe ẹri agunbanirọ:

Ó fi kun gbogbo ètò ìgbé ayé òun wá dúró sójú kan nítorí ìjákulẹ̀, ìtìjú àti onírúurú ọ̀rọ̀ òdì tí àwọn ènìyàn ń sọ sí òun.

Ó ní "ipò tí wọ́n fi mi gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fétò ìsúná tí kọ́kọ́ ṣokùnfà kí àwọn kan máa gbógun ní ìbẹ̀rẹ̀ sáà náà, ìgbà tí inú mí wá ń dún pé ohun gbogbo ti ń bọ́ sípò ni ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí náà yọjú, àkókò tó le jù fún mi nínú ìgbé ayé mi ni".

"Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti gba orí ẹ̀rọ ayélujára tí gbogbo rẹ̀ sì di ranto, òun tó dùn mí jù ni pé n kò rẹ́nu ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan tí òun sì kọ̀wé fipò sílẹ̀.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit

Alaye ree lori bi ayederu iwe ẹri agunbanirọ se de ọwọ mi:

Mínísítà tẹ́lẹ̀ náà ṣàlàyé pé orílẹ̀ èdè United Kingdom ni wọ́n bí òun sí, tí wọ́n sì tọ́ òun níbẹ̀ àti pé títí tí òun fi pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, òun kàn máa ń wá sí Nàìjíríà fún ìsinmi lásán ni.

Adeosun ní òun parí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ẹni ọdún mọ́kànlélógún tí òun sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́ni ọdún méjìlélógún ní orílẹ̀ èdè United Kingdom.

Ó ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ni òun darí wá sí Nàìjíríà láti máa gbé, nígbà náà ní òun ṣe ìbéèrè bóyá òfin NYSC náà kan òun.

"Wọ́n sọ fún mi wí pé nítorí tí mo ti lé ní ọmọ ọgbọ̀n ọdún, mi ò lè sin ìlú mọ́ pé ohun ti mo nílò ní ìwé ẹ̀rí wí pé NYSC yọ̀ǹda mí".

"Èyí ló mú mi kàn sí àwọn tí mo rò wí pé mo fi ọkàn tán láti bá mi gba ìwé ẹ̀rí náà ṣùgbọ́n èmi kò mọ̀ wí pé ẹni ti mo gboju okun le, kò jọ ẹni agba".

"Mo gba ìwé náà sọ́wọ́ láìmọ̀ wí pé ayédèrú ni, mo sì ti lò ó ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun lọ́dún 2011 àti lọ́dún 2015 ní ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àti ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ fún àyẹ̀wọ̀ láìsí ìdíwọ́ kankan.

Àkọlé fídíò, 'Tóo bá lè bá mi jà, ìwọ wá!' Ademodi Maria tó lu ọmọdékùnrin mìí lálùbami rèé

Ojoojúmọ́ ni mo fi sunkún fún oṣù mẹ́ta:

"Ojú gbà mí tì gan nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ògo wẹẹrẹ ni mo ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún nígbà náà, tí ìròyìn sì lòdì sí ohun tí mò ń kọ́ wọn".

Adeosun ṣàlàyé pé kòdá lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ fọ òun mọ́ ojoojúmọ́ ni oun fi n sunkún fún ọdún mẹ́ta nítorí ọ̀rọ̀ náà, kòdá òun lọ fún àyẹ̀wò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kí òun tó le kó ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn.

Ó ní lẹ́yìn ọdún mẹ́ta ní òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ọ̀rọ́ náà kúrò lára.

Ta ni Kemi Adeosun:

Kemi Adeosun ni Minisita tẹlẹ fun eto isuna ni Naijiria laarin ọdun 2015 si 2018.

Akọsẹmọsẹ nipa isisro nii se, to si kawe ni ilu ọba UK, ko to wale wa kopa ninu eto oselu.

Lọjọ Keje osu keje ọdun 2018 ni iwe iroyin kan kede sita pe ayederu iwe ẹri agunbanirọ ni minisita naa lo lati gba ipo oselu.

O si wa ninu ofin Naijiria pe ẹnikẹni ti yoo ba gba ipo oselu tabi du ipo oselu gbọdọ ni ojulowo iwe ẹri isinru ilu taa mọ si NYSC tabi ko gba iwe ẹri pe wọn yọnda rẹ lati sinru ilu.

Auyewuye lori ọrọ lilo ayederu iwe ẹri naa lo mu ki Kemi Adeosun kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii Minisita, to si pada silu ọba.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀