Kaduna Airport Attack: Àwọn agbofinro tí kojú ikọlù tó wáyé ní papakọ òfurufú, iṣẹ bẹ̀rẹ̀ padà-Ìjọba

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn janduku agbebọn kan yabo agbegbe papakọ ofurufu ipinlẹ naa ti wọn si pa eeyan kan.
Eeyan kan ti wọn lo padanu ẹmi rẹ yi jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n mojuto ọrọ papakọ ofurufu ni Naijiria taa mọ si NAMA.
Samuel Aruwan to jẹ kọmisana feto aabo labẹlẹ ni Kaduna lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC.
- Márosẹ̀ Kaduna di ìbùba fáwọn ajínigbé
- Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí Gúúsù Kaduna ní ìkọlù àwọn agbébọn sí NDA kìí ṣe ìyàlẹ́nu
- Wọ́n tí dóòla ọmọogun Major Datong tí àwọn agbébọn jígbé lásìkò ìkọlù sí NDA
- Ìròyìn ayọ̀! Emir tí wọ́n jígbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀, báwó ló ṣe ṣeé láàrin ọ́jọ́ méjì?
- Agbébọn pa ènìyàn 14, ọmọọ̀gun Naijiria sígun ni Kaduna
Iṣẹlẹ yi waye lọsan ọjọ Abamẹta tawọn ileeṣẹ iroyin kan si sọ pe o mu idiwọ ba iṣẹ ni papakọ ofurufu naa lasiko ti awọn agbebọn yi fi ṣoro.
Amọ ṣa Aruwan ni gbogbo nkan ti pada sipo bayi lyin ikoju awọn agbofinro ti awọn baalu si ti n gbera pada.
Ko sọ iye awọn janduku agbebọn yi tabi boya wọn ri ẹnikankan mu ninu wọn.
Ipinlẹ Kaduna jẹ ibi ti ipenija aabo ti jẹ ohun to n kan araalu lominu .
Bi wọn ko ba maa ronu ikọlu awọn agbebọn si ile ẹkọ ti wọn si n ji akẹkọọ gbe, niṣe ni ifoya maa n ba araalu lori ijingbe lawọn oju popo.
Bi a ko ba gbagbe awọn agbebọn kan ti fi igba kan yawọ ọgba awọn ọmọogun Naijiria ni NDA to wa ni Kaduna ti wọn si pa eeyan meji ki wọn to ji gagun kan gbe salọ.
Igba akọkọ ree ti awọn afurasi agbesunmọmi yoo laya wọ inu papakọ ofurufu ti wn ko si ni ri eeyan kankan mu ninu wọn.
Iṣẹlẹ yi n waye lonii ti ṣe ọjọ ti Gomina Kaduna Nasir El Rufai n darapọ mọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC miran lati yan awọn ti yoo dari eto ẹgbẹ naa.
Gomina Kaduna ninu atẹjade ti Aruwan fi sita ba awọn mọlẹbi ni to ku ninu iṣẹlẹ naa kẹdun.















