2022 APC National Convention: Àwọn nǹkan tó yẹ ko mọ̀ rèé nípa alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC tuntun

Abdullahi Adamu

Oríṣun àwòrán, Channels

Àkọlé àwòrán, Abdullahi Adamu

Ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC yan àwọn adarí tuntun tí yóò máa tukọ̀ ẹgbẹ́ náà fún ọdún mẹ́rin.

Sẹ́nétọ̀ Abdullahi Adamu ni alága tuntun fún ẹgbẹ́ náà nígbà tí gbogbo àwọn tó jọ ń díje jọ̀wọ́ ipò náà fun lẹ́yìn tí gbogbo wọn fẹnukò láti yàn án níbi àpérò àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà tó wáyé ní Eagles Square, Abuja.

Ṣaájú ni ìròyìn ti gbòde wí pé Adamu ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ń fẹ́ kí ó di alága ẹgbẹ́ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Òun ni yóò máa gba àkóso lọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe, Mai Mala Buni tó ti ń ṣe àkóso ẹgbẹ́ láti ìgbà tí wọ́n ti yẹ àgá mọ́ Adams Oshiomole nídìí lọ́dún 2020.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Ta ni Abdullahi Adamu?

Abdullahi Adamu jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lọ́wọ́lọ́wọ́ tó ń ṣojú ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Nasarawa.

Bákan náà ló ti fi ìgbà jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2007.

Ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje, ọdún 1946 ni wọ́n bi sí ìlú Keffi ìpínlẹ̀ Nasarawa, tó sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní níbẹ̀ kó tó tẹ̀síwájú láti lọ parí ẹ̀kọ́ girama ní Government Secondary School, Makurdi, ìpínlẹ̀ Benue láàárín ọdún 1960 sí 1962.

Lẹ́yìn èyí ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Government Technical College, Bukuru, kó tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Kaduna láti gba ìwé ẹ̀rí HND.

Ní ọdún 1992 ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga UNIJOS tó sì di amòfin lọ́dún 1993.

Ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lọ́dún 1977 ní ìrìnàjò Adamu nínú òṣèlú bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n yàn án sínú ìgbìmọ̀ tí yóò kọ ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí fún ìgbà sáà kejì ìjọba alágbádá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Bákan náà ló tún wà nínú ìgbìmọ̀ tó rí sí àpérò ìwé òfin tí Sani Abacha yàn lọ́dún 1994.

Ní ọdún 1999 ló gbégbá ìbò láti díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Nasarawa tó sì jáwé olúborí fún sáà méjì.

Bákan náà ló jẹ alága àkọ́kọ́ ẹgbẹ́ àwọn gómìnà orílẹ̀ èdè yìí nígbà tí wọ́n da sílẹ̀ lọ́dún 1999, ipò tó jẹ́ fún ọdún márùn-ún.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Kíni àwọn iṣẹ́ tó wà níwájú Adamu

Àkọ́kọ́ kókó iṣk kan gbòógì tó wà níwájú Adamu gẹ́gẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni rírí dájú pé ẹgbẹ́ náà mókè níbi ètò ìdìbò gbogbogboò lọ́dún tó ń bọ̀.

Ó gbọ́dọ̀ ri dájú pé olùdíje tí yóò kájú òṣùwọ̀n ní ẹgbẹ́ fà kalẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ máa jẹ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣèjọba lọ lọ́dún 2023.

Bákan náà ni kó ri dájú pé àláfíà jọba láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ pàápàá àwọn tó ń fapá jánú.

Amin iyasọtọ kan

Abdulahi Adamu di alága àpapọ̀ tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC:

Abdullahi Adamu
Àkọlé àwòrán, Abdullahi Adamu

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe wọn ti yan Alhaji Abdullahi Adamu gẹgẹ bi alaga tuntun fẹgbẹ oṣelu APC nibi ipade gbogbo ọmọ ẹgbẹ to waye nilu Abuja lọjọ Satide.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti gbogbo awọn oludije yoku fun ipo naa jawọ, ti wọn si fi ohun ṣọkan pe ki Adamu wọle lai dibo.

Pupọ awọn ipo adari ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria ni wọn wọle laidibo, yala nitori aisi ẹni to n ba wọn du u tabi lẹyin ti awọn ti n ba wọn du u jawọ ninu idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Abubakar Badaru kede oruko awọn ti ọrọ ipo wọn ti yanju lati wọle laidibo, lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye lori ta ni yoo dari ẹgbẹ oselu naa.

Bẹẹ ba si gbagbe, ipinnu ọhun lo waye lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹsan ti wọn tu igbimọ adari ẹgbẹ APC ka.

Awọn ọmọ ẹgbẹ APC nibi ipade gbogbo gboo atawọn ẹsọ alaabo

Ṣaaju ni iroyin ti fọn sita nipa iwe orukọ awọn ti wọn fẹnuko si lati dari igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oselu naa ni igbaradi fun idibo apapọ ọdun 2023 eyi ti wọn pe ni "Unity list"

Bi o tilẹ jẹ pe awon alakoso idibo naa rawọ ẹbẹ sawọn oludije kan lati forikori fun oludije kan soso lati wọle laiwulẹ seto dibo mọ, sibẹ awọn kan ninu awọn oludije faake kọri pe awọn ko ni gba.

Awọn ẹgbẹ fikunlukun lati yan asoju ẹgbẹ

Amoṣa lẹyin ọpọ ifikuluku, awọn kan lara wọn gba fun ifẹnuko.

Lara awọn irufẹ ipo bẹẹ ni ipo igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oselu APC fun ẹkun ariwa orilẹede Naijiria ati ipo akọwe ẹgbẹ oṣelu APC.

Eyi to gbajumọ ju ninu awon wonyi ni ipo akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu naa laarin Amofin Adebayọ Shittu, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Olaiya Olaitan ati Ifeoluwa Oyedele.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit

Iyiola Omiṣore ni akọwe apapọ ẹgbẹ APC

Lẹyin ọpọ ifikuluku, ipẹtusininu ati ipẹ, awọn oludije yoku jọwọ rẹ silẹ fun Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore.

Bẹẹ lawọn ipo tawọn oludije ko ti ju ọwọ silẹ funrawọn wọ inu abala idibo lọ lati dibo.

Emmanuel Ekechukwu ni wọn gba wọle gẹgẹ bi igbakeji alaga APC fun ẹkun gusu lẹyin ti Sẹnetọ Ken Enamani to n ba a du ipo naa ju ọwọ silẹ lori pe gẹgẹ bi agba ẹgbẹ, ibi gẹrẹjẹ la n ba agba.

Ahmad Usman ElMazuk ni wọn yan ni ipo olubadamoran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ naa lapapọ.

Ẹgbẹrun meje o le ọrinlelẹẹdẹgbẹta ati mẹrin awọn aṣoju ni wọn wa sibi idibo naa ṣugbọn eto ifẹnuko yan oludije kan ti oloyinbo n pe ni "conscensus" lo dabi ẹni pe awọn idibo naa ba lọ.

Ṣaaju eto idibo yan awọn adari ẹgbẹ naa to waye nilu Abuja lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹta ọdun 2022, ko din ni igba mẹta ọtọtọ ti APC ti gbero ati ṣe eto idibo naa ṣugbọn ti n ja si pabo.

Gẹgẹ bi igbimọ to n seto akoso idibo naa ṣe sọ, gbogbo awọn ti jawo ninu idije naa lẹyin ifikuluku pẹl'awọnadari ẹgbẹ naa yoo gba owo ti wọn fi ra fọọmu idije wọn pada.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

Bí ẹ bá fipá yan olùdíje lé ẹgbẹ́ lórí, yóò bu yín lọ́wọ́, Buhari gba ìgbìmọ̀ adarí tuntun ní APC lámọ̀ràn

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ke s'awọn aṣiwaju tuntun ti ẹgbẹ naa ṣẹṣẹ gbe kalẹ lati fẹsọ ṣe lori ọrọ a n fi ipa yan oludije lori ẹgbẹ.

Aarẹ Buahri ṣalaye pe ko si bi wọn ba ti rawọ le fifi ipa yan oludije kan le ẹgbẹ lori ṣaaju idibo apapọ ọdun 2023 ti ko ni bu wọn lọwọ.

Aarẹ Buhari sọrọ yii lasiko to n ba awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri igun mẹrin Naijira sọrọ nibi ipade ati yan awọn adari apapọ lẹgbẹ naa ti waye ni gbagede Eagle Square nilu Abuja lọjọ Satide.

Aarẹ Buhari fa awọn omo igbimọ iṣakoso apapọ tuntun lẹgbẹ oselu APC naa leti pe ki wọn fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ lanfani aparo kan ko ga jukan lọ lati dije fun ipo yoowu ti wọn ba fẹ, eyi to pe ni ọpakutẹlẹ fun idagbasoke iṣejọba tiwantiwa.

Aarẹ orilẹede Naijiria wa rọ awọn ọmọ igbimọ tuntun naa lati gba eto tiwantiwa laarin ẹgbẹ laaye ki wọn si rii daju won ko sọ idibo ati yan oludije fun ipo oṣelu di owo ree ọja ree lọ.

Bakan naa lo rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati yanju gbogbo aawọ to ba wa laarin wọn ni tubinubi ki wọn si ṣugba awọn adari tuntun naa lati tubọ sun ẹgbẹ oṣelu APC siwaju.

Amin iyasọtọ kan

Ìdìbò àwọn adarí ẹgbẹ́ APC ń wáyé ní Sátidé, wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń díje:

Awọn adari ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, APc

Ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ni ipagọ apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC yoo waye nilu Abuja.

Gbagede Eagles Square ni eto naa yoo ti waye, ti ireti si wa pe aṣoju ẹgbẹ APC, bi ẹgbẹrun mẹrin lati awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria, ni yoo kopa.

Nibi ipagọ naa ni wọn o tun ti dibo awọn adari ẹgbẹ naa.

Iroyin sọ pe eeyan mọkandinlaadọsan lo ti gba fọọmu lati dije fun ipo mejilelogun ti wọn fẹ ẹ dibo yan.

Botilẹ jẹ pe ko si ẹni to n dije fun ipo alaga ẹgbẹ, tabi igbakeji rẹ, lati ẹkun Iwọ-oorun Gusu, ao ṣe afihan awọn to n dije fun awọn ipo yooku.

Awọn ẹkun ti APC fun ni ipo kọọkan

  • Aarin gbungbun Ariwa (North Central) - Alaga ẹgbẹ
  • Ila oorun Ariwa (North East) - Igbakeji alaga ẹgbẹ
  • Ila oorun Gusu (South East) - Igbakeji alaga ni Gusu
  • Iwọ oorun Ariwa (North West) - Igbakeji alaga ni Gusu
  • Iwọ oorun Gusu (South West) - Igbakeji alaga ni Gusu
  • Iwọ oorun Gusu (South West) - Akọwe apapọ ẹgbẹ
  • Iwọ oorun Ariwa (North West) - Akọwe ikede
  • Gusu-Gusu (South-south) - Olori obinrin
  • Awọn oludije lati ẹkun Iwọ oorun Gusu

Eeyan mẹrin lo n dije fun ipo akọwe gbogboogbo fun ẹgbẹ oṣelu APC lati Gusu Iwọ-oorun Naijiria to wa.

Eyi wa ni ibamu pẹlu ilana ẹgbẹ naa to ni ẹkun ọhun ni akọwe yoo ti wa.

Miliọnu mẹwaa Naira ni ọkọọkan wọn ra fọọmu idije.

Igbakeji gomina ipinlẹ Osun nigba kan, Iyiola Omisore, minisita fun eto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ, Adebayo Shittu lati ipinlẹ Oyo, Olaiya Olaitan ati Ife Oyedele.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Idije fun onirruru ipo ninu ẹgbẹ naa ko yọ awọn obinrin silẹ.

Ọmọ oloogbe MKO Abiola, Kareemat Abiola naa n dije fun ipo olori ọdọ.

Awọn miran to fẹ du ipo naa mọ lọwọ ni Dada Olusegun, Dayo Idrael, Olalekan Edwards ati Buhari Sadeeq.

Ẹ tẹti leko loju opo yii lati mọ bi ipagọ naa ati eto idibo ti yoo waye nibẹ yoo ṣe lọ.