Timothy Adegoke Vs Rahmon Adedoyin: Ẹbí Adedoyin korò ojú sí ọ̀rọ̀ tó ń lọ lórí ayelujára nípa ìgbẹ́jọ́ wọn

Adedoyin nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, others

Igbẹjọ lori iku to pa Ọgbẹni Timothy Adegoke tẹsiwaju loni ni ile ẹjo giga ipinlẹ Osun lẹyin ti bi Adedoyin sọ ninu igbẹjọ to kọja pe awọn n bọ wa tọrọ aṣẹ lonii lati ma gbẹjọ mọ.

Amofin Yusuf Alli to ṣoju idile Adedoyin ṣee lalaye pe ọpọlọpọ idajọ ọwọ ara ẹni lo ti kun oju opo ayelujara (social media) ti ko si ni nkankan se pẹlu ohun to n ṣẹlẹ gangan ni pato.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit

Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe ọrọ yii ti kọja eyi ti awọn ara Osun mọ si bayii amọ o ti di ti gbogbo agbaye ti awọn eeyan si n ja fun idajọ ododo fun iku Timothy Adegoke.

Adedoyin n wọ ile ẹjọ
Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante

Tori naa ni gbogbo ori ayelujara ṣe n gbona giri ni gbogbo igba ti ile ẹjọ ba ti n joko lori rẹ.

Agbẹjoro Alli bẹ ile ẹjọ lati lo awọn ẹri ti wọn mu wa si ile ẹjọ ati atotonu awon eleri lati gbe idajọ rẹ kalẹ.

O ṣalaye pe ofin orilẹede Naijiria ko faye gba ki "a bẹ eṣe ọmọ wo lara baba tabi iya rẹ nitoripe ko si ẹni to le tọka si Adedoyin pe o lọwọ ninu iṣẹ naa.

Adedoyin n wọ ile ẹjọ

Agbẹjọro Muritala Abdulrosheed pe fun itusilẹ eeyan mẹta ninu awọn ti wọn fesun kan.

Muritala ṣalaye pe mẹta ninu wọn ni ko ni ibaṣepo tabi ifarakinra pẹlu oloogbe Timothy Adegoke.

Muritala ṣalaye pe awon mẹtẹẹta ọhun ni ko si ni ikalẹ nigbati Timothy Adegoke wọle sinu ile itura Hilton nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

Ọkọ ti wọn fi gbe Adedoyin jade

Agbẹjọro fun ijọba Mathew Omosun bẹ ile ẹjọ lati ma ṣe gba atotonu awọn agbẹjọro yii ku lori idasilẹ "a ko lẹjọ ro ti wọn gbe wa si ile ẹjọ".

Agbẹjọro Mathew ṣalaye pe gbogbo awọn to wa si ile ẹjọ lati jẹri ni wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu oun ti wọn yan laayo.

Adajọ agba Adepele Ojo sun igbẹjọ si Ọjọru Ọsẹ to mbọ lati gbe idajọ kalẹ lori oun ti wọn mu wa si ile ẹjọ lori "idasilẹ a ko lẹjọ ro".