Amodu Abubakar Vigilante's hands cut off by suspected Fulanis: Mo fẹ́ mu ìbọn ni mo ríi pé ọwọ́ mi ti gé jọ́bọ́
"Mi o le da sokoto bọ, mi o le mu ọwọ lọ ẹnu fi jẹun, mii le fi mu nkan kan mọ".
Amodu Abubakar jẹ ọkan lara awọn Fijilante to n ṣọ adugbo ni agbegbe Iwajowa Itasa to fi dede kan agbako awọn afurasi Fulani to ni wọn ge oun lọwọ.
Amodu ni oun lọ ile lati ibi to ti n ṣiṣẹ ni ọjọ Ẹti ni nkan bii ago marun irọlẹ ni iṣẹlẹ aburu yii ṣẹlẹ.
O ni oun de ọna ni apaa Oyan ni oun ba awọn Fulani meji ti wọn n mu omi lodo ti oun si kọja lọ, amọ nigba ti ilẹ yoo fi su ba oun lọna ni awọn Fulani meji kan naa ti oun ri dede ke oun lori ọkada ti wọn si bẹrẹ si ni ṣa a ni iṣakuṣa pẹlu ada.
O ni bi oun ṣe fẹ gbe ọwọ ki oun mu ibọn fi yin in ba wọn loun rii pe ọwọ rebọ.
Iroyin naa tẹwa lọwọ pe awọn afurasi Fulani ọhun ṣọọ titi ti ilẹ fi su baa lọna ibi to n lọ.
Ọba Michael to jẹ olori ilu naa fia ridaju iṣẹlẹ yii han fun BBC Yoruba.


