Fulani Herdsmen attack: Gbogbo ẹni tó bá para kò ní rí ojú 'rere Ọlọ́run, Fulani ló dá wa
Ọpọlọpọ igba ni iroyin ti tan ka pe awọn Fulani darandaran n ṣe ọṣ kaakiri ilẹ Yoruba ti awọn araalu si n figbe ta amọ niwọn igba ti ijọba ko ti fi oju Fulani kankan han gẹgẹ bi ọdaran, afurasi lasan naa ni awọn oniroyin lee pe wọn.
Ẹwẹ, awọn ọmọ Yoruba n pariwo pe yala ijọba gba tabi wọn ko gba, awọn ti ni iriri ikọlu fulani ti awọn ko si lee fibo tori ifarapa ti wọn la kọja.
Lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ ni Alhaji Jubril Alabi Adedapo to ṣalaye pe loṣu kẹfa yii gan ni awọn Fulani kọlu oun.
"Tori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ laarin Eko, a ni ka gba ilu Ijebu Ode ka le gba Epe jade si Lekki ni a gbọ iro ibọn latinu igbo, awọn ọlọdẹ la ro pe wọn n yinbọn afi ti wọn da ibọn bolẹ lai duro".
O ni ọna daru tobẹẹ ti ọkọ oun gba eyi to wa lẹyin ati ti ọkọ to jina si awọn si fere gee amọ wọn da ibọn bo o.
Alhaji Jubril ni gbogbo awọn to jade si awọn ninu igbo, Fulani ni wọn.
Jubril sọrọ ilẹ kun nipa iriri rẹ fun BBC Yoruba.

