Ademodi Maria 12 year old boxer: Mo máa kọ́kọ́ bí ẹ́ pé ṣé o lè nà mí kí n tó wá fi àgbà hàn ẹ́

Àkọlé fídíò, 'Tóo bá lè bá mi jà, ìwọ wá!' Ademodi Maria tó lu ọmọdékùnrin mìí lálùbami rèé

"Mi o ki n ja ẹṣẹ ni ile-ẹkọ mi toripe wọn fun wa ni ofin ti a n tẹle. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ile ẹkọ mi maa n dan mi wo pe ṣe tori mo n ja ẹṣẹ, ṣe mo le wa lu wọn ni...".

Laipẹ ni fidio kan gba ori ayelujara kan lẹnu ọjọ ranpẹ sẹyin ti ọmọdebinrin kan lu ọmọdekunrin ni alubami ninu idije jija ẹṣẹ.

Fidio yii ti n fa ọpọlọpọ esi lori ayelujara ti awọn n wo pe o ri bakan bakan ki obinrin na obinrin. Awọn mii tilẹ n sọ pe irọ ni, ọmọkunrin yẹn kan fun un ni ọwọ pe o jẹ obinrin ni ko ṣe lu u.

Amọ ni tiwa ninu fidio ti awa ri o, alubami, alubolẹ, alu-rọ-iyẹpẹ si ni lẹnu gbaa ni "Ẹṣẹ Maria" ma lu ọmọdekunrin ti wọn jọ n ṣe idije yii.

Ni BBC Yoruba ba gbera lati wa Maria lọ pe "n gbọ bawo lo ṣe ṣe e too si rọ ẹṣẹ si eyin, mọ oju ẹnu ati gbogbo ori ọmọkunrin to n ba ja?"

Eyi lo mu ki Maria kẹnu bọ ọrọ to ṣalaye awọn nkan to maa n fi akoko rẹ ṣe to fi di alagbara abẹṣẹkubiojo.

Koda baba rẹ naa ba BBC sọrọ bi ko ṣe de e lọna ati ṣe ohun to wu u amọ ti ko jẹ ko di ẹkọ rẹ lọwọ ti wọn si sọ awọn ẹṣin iwaju to n wo ninu iṣẹ kikan ẹṣẹ gba ẹyẹ.