OAU VC: Ooni Ile-Ife sọ pé ìwọ́de tako ìyànsípò VC tuntun ní OAU kò tako òfin

Oríṣun àwòrán, ooni of ife
Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, ti kilọ fun awọn ọmọ bibi ilu naa ati awọn to n gbe nibẹ, lati má gbe igbesẹ to tako ofin lori iyansipo ọga agba Fasiti Obafemi Awolowo, OAU.
Ninu atẹjade kan ti oludari ẹka ikede ati iroyin fun Ooni, Moses Olafare, fi sita lọjọ Iṣẹgun, ni Ooni Ogunwusi ti fi da awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ fasiti naa loju pe aabo yoo wa fun wọn.
Ọjọ Aje ni awọn ọmọ ẹgbẹ ibilẹ kan ṣe iwọde lẹnu iloro ile ẹkọ naa, lati tako iyansipo Ọjọgbọn Adebayo Bamire gẹgẹ bi ọga agba tuntun, VC.
Awọn onitọhun sọ pe awọn tako yiyan ẹni ti kii ṣe ọmọ ilu Ile-Ife gẹgẹ bi ọga fun fasiti naa.
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ́ fún ìyá tó lu olùkọ́ ọmọ rẹ ní Ogun láti gbá ọgbà ilé ẹ̀kọ́ nàá fún oṣù mẹ́fà
- Mọ̀ nípa ìlànà tí wọ́n n gbà yan ọ̀gá àgbà Fásítì, VC ní Naijiria
- Gómìnà Oyetola rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlù atí Oníṣẹ̀ṣe tó fẹ̀hónúhàn ní OAU torí VC tuntun tí kìí ṣe ọmọ ìlú
- 'Ọjọ́ méjì àti wákàtí díẹ̀ péré la fún Ramon Adedoyin láti gbé ìwée 'a kò ní ẹjọ́ jẹ́' wá sílé ẹjọ́'
Ooni sọ ninu atẹjade naa pe lootọ ni awọn oluwọde ọhun ni ẹtọ labẹ ofin, lati fi ẹhonu wọn han nipa iwọde, o ni ṣugbọn wọn ko gbọdọ ṣe e lọna to le mu ewu ba alaafia ati eto aabo ilu.
Bakan naa lo sọ pe oun ti n jiroro pẹlu awọn alẹnulọrọ, fun ijiroro ati igbesẹ to yẹ lori ọrọ yii.
O ni "ko si ohunkohun ti yoo ba ajọṣepọ to wa laarin ilu Ile-Ife ati fasiti OAU jẹ, paapaa fun anfaani awọn ọdọ ni Fasiti naa ati kaakiri agbaye".















