Student beats teacher: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ìyá tó lu olùkọ́ ọmọ rẹ̀ ní Ogun lọ gbá ọgbà ilé ẹ̀kọ́ nàá fún oṣù mẹ́fà

Ile ẹjọ Majisireti kan nilu Ota, nipinlẹ Ogun, ti paṣẹ fun arabinrin kan, Elizabeth Joshua, lati gba ilẹ ọgba ile ẹkọ ọmọ rẹ fun oṣu mẹfa gbako.
Ọwọ ọlọpaa tẹ Abilekọ Joshua ninu oṣu kẹta, ọdun 2021, lẹyin to ko awọn janduku lọ si ile ẹkọ Iju-Ebiye High School, nijọba ibilẹ Ado Odo/Ota , lati lu awọn olukọ ọmọ rẹ.
Awọn ọlọpaa fi ẹsun kan an nile ẹjọ pe o sowọpọ mọ awọn kan lati fiya jẹ awọn olukọ, wọn ni o lu awọn olukọ, o si tun da alaafia ile ẹkọ ru.
Ninu idajọ to ṣe ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, onidajọ Shotunde Shotayo, paṣẹ fun obinrin naa pe ko ma a gbá ilẹ ile ẹkọ naa lati aago mẹjọ owurọ si aago mọkan owurọ lojoojumọ.
- Akẹ́kọ̀ọ́, ìyá rẹ àtàwọn jàndùkú dá bàntẹ́ ìyà fún olùkọ̀ọ́ l'Ogun
- Mọ̀ nípa ìlànà tí wọ́n n gbà yan ọ̀gá àgbà Fásítì, VC ní Naijiria
- Gómìnà Oyetola rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlù atí Oníṣẹ̀ṣe tó fẹ̀hónúhàn ní OAU torí VC tuntun tí kìí ṣe ọmọ ìlú
- Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀ tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti
Bakan naa lo tun sọ fun awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa pe ki wọn o ṣi iwe kan fun , nibi ti wọn o ma kọ akọsilẹ nipa bo ṣe n ṣiṣẹ naa to lojoojumọ.
Yatọ si eyi, Onidajọ Shotayo tun sọ pe Arabinrin Joshua gbọdọ san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira fun ọga ile ẹkọ naa ati olukọ to farapa lasiko ikọlu ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ihuwasi arabinrin naa tako ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006.
Awọn akẹkọọ ati obi tun lu olukọ ọmọ wọn nipinlẹ Ogun
Ni oṣu Kinni, ọdun 2022, ni iroyin sọ pe iya kan, Elizabeth oshua, lu awọn alaṣẹ ile ẹkọ Toyon High School, Ota, nitori pe wọn ko faaye gba ọmọ rẹ, Joshua Joseph, lati wọ kilaasi, nitori iru irun to ge si ori.
Olukọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọgbẹni Kabir Azeez la gbọ pe o ni ki Joshua lọ ọ tun irun ori rẹ ge, ko to o le wọ kilaasi, lẹyin ti wọn ti kilọ fun bi ọjọ meji.
Ṣugbọn, nigba ti yoo pada sile ẹkọ, oun, iya rẹ, ati awọn janduku lo wa, ti wọn si kọju ija si awọn olukọ.
Olukọ bii mẹrin ni iroyin sọ pe wọn lu, ti wọn si tun fọ gilaasi ọkọ ayọkẹlẹ ẹnikan lara wọn.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin bi ọsẹ meji ti ijọba ipinlẹ Ogun fun awọn obi ni iwe lati fọwọ si pe awọn ọmọ wọn ko ni i da ile ẹkọ ru.
Ijọba gbe igbesẹ naa nitori bi awọn akẹkọọ ṣe n kọlu awọn olukọ wọn ni awọn agbegbe kan nipinlẹ naa.
















