Nyesom Wike 2023 :Àwọn tó ṣe àkóbá fún wà ní 2015 ló n wà tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ fún 2023

Oríṣun àwòrán, Facebook/Jimin Geoffrey
Gomina ipinlẹ Rivers Nyesom Wike ti kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Wike fidi ọrọ yi mulẹ ni ilu Makurdi lọjọ Aiku.
O ni oun ni ikapa lati koju ẹgbẹ alaburu APC nii to si kesi gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ rẹ ni PDP lati gbaruku ti oun.
- Gomina Wike fi òfin de iṣẹ́ aṣẹ́wó, Night Club, kátàkárà alẹ́ àti àwọn nkan míràn
- Tí Obasanjọ bá fi PDP sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ PDP kò lè kúrò lára rẹ- Iyorchia Ayu. Alágá PDP
- Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Iyorchia Ayu tó dí Alágá tuntun fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP
- Ìdí rèé tí mo fí kọ PDP sílẹ, lọ darapọ̀ mọ́ APC- Ben Ayade
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
O ni oun ko fi ẹgbẹ silẹ lasiko tawọn eeyan kan n sa lọ si ẹgbẹ miran ati pe oun gbiyanju lati ri pe ẹgbẹ PDP ri atunto eleyi ti gbogbo eeyan n gbadun loni.
Lara nkan ti Wike sọ pe oun yo koju gẹgẹ bi aarẹ Naijiria ni ipenija aabo to n koju Naijiria.
Bẹẹ lo s pe oun ko ni maa paṣẹ lati jina bi kii ṣe pe ki oun l si oju ibi ti aṣẹ ba ti nilo pipa.
Àwọn tó ṣe àkóbá fún wà ní 2015 ló n wà tikeeti ẹgbẹ́ fún 2023
Ninu ọrọ rẹ to sọ fawọn akọroyin ni Makurdi, Nyesom Wike sọ pe awọn to koba ẹgbẹ PDP ni 2015 lo n jija du tikẹẹti ẹgbẹ bayi.
''Gbogbo awọn to fẹ di aarẹ nisinyi ni wọn da wahala silẹ fun ẹgbẹ wa ni 2015 nigba ti wọn kora jọ lati gbegi dina aṣeyri wa nigba naa''

Oríṣun àwòrán, Facebook/Jimin Geoffrey
''Wọn salọ nigba ti ẹgbẹ nilo wọn julọ ṣugbọn gbọin lemi duro lẹyin ẹgb. Mi o nibi ti maa salọ nitori mo fi sọkan pe ẹgbẹ yi ko gbọdọ ku''
Yatọ si Atiku Abubakar to ti kede erongba rẹ ninu ẹgbẹ PDP Nyesom Wike ni o fẹ ẹ tẹle lati fi erongba rẹ han.
- Èkó àti Rivers nìkan kọ, wo àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù mi tó ṣetán láti lọ sílé ẹjọ́ gíga jùlọ lórí VAT
- Àrùn ibà mú PDP, jẹjẹrẹ mú APC, n kò lè fi PDP sílẹ̀ láé lọ APC - Wike
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Wike pàṣẹ kí agbófinró mú kọngílá ilé tó wó ní Portharcourt
- Àwọn gómìnà PDP parí ìpàdé, wọ́n ní Buhari ti dojú ọrọ̀ ajé Nàìjíríà rú
Gomina ipinlẹ Rivers yi ti ṣaaju ṣe Kọmisana ni ipinlẹ Rivers ko to di Minisita feto ẹkọ lorileede Naijiria labẹ ijọba Goodluck Jonathan.
Lẹyin to fi ipo Minisita silẹ lo gbe apoti ibo Gomina ipinlẹ Rivers.
Ninu awọn eekan ti ko jẹ ki aṣọ yẹ lejika ẹgbẹ PDP ni Wike wa to si ṣiṣẹ debi pe ipinlẹ rẹ fẹsẹrinlẹ gẹgẹ bi ipinlẹ ti PDP ti jọba.












