Olusegun Obasanjo: Ààrẹ àná orílẹ́èdè Nàìjíríà ní òun ò lè padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́ láyé

Iyorchia

Oríṣun àwòrán, @Ayu

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣalaye fawọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn ṣepade pọ pẹlu rẹ pe oun ko le pada sinu ẹgbẹ naa mọ laye.

Obasanjo sọrọ yii nigba ti alaga gbogbogbo PDP, Iyorchia Ayu ati awọn gomina tẹlẹ ri mẹrin to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ amuṣẹya PDP kan si i nile rẹ niluu Abeokuta lọjọ Abamẹta.

Peter Obi, gomina Anambra tẹlẹ ri, Sule Lamido, Jigawa, Olusegun Mimiko Ondo, Liyel Imoke Cross River ati Donald Duke ti ipinlẹ Cross River bakan naa lo kan si Obasanjo nile rẹ.

Kini Obasanjo sọ?

Ó doódì! Mi ò lè padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́ láyé- Obasanjo yarí

''Mi o ṣe oṣelu mọ, ko si si ohun to le dami pada sinu oṣelu.

Olusegun Obasanjo

Ẹnikẹni to ba nilo amọran tabi itọsọna lati ọdọ mi le wa, maa fi tayọ tayọ gba iru ẹni bẹẹ ni imọran.

Mo wa fun gbogbo nkan to ba le mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Obasanjo salaye pe: N ko le gbagbe PDP laye ninu ohun gbogbo ti mo ba ṣe, tori ẹgbẹ PDP lo gbemi wọle ibo aarẹ lẹẹmeji.

Lati ọjọ ti mo ti fa kaadi ọmọ ẹgbẹ PDP mi ya ni mo ti dagbere fun ẹgbẹ naa gẹgẹ bi ọkan lara ọmọ ẹgbẹ.

Ọjọ naa ni pinnu lati ma darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan mọ,''

Àkọlé fídíò, Kaun

Aarẹ ana Naijiria sọ fun Ayu pe ẹru iṣoro PDP ati ti Naijiria lo wa lejika rẹ, o si gbadura fun un pe Eledua yoo fun un lọgbọn lati gbe ẹru naa.

Esi wo ni Ayu fi da Obasanjo lohun?

Ninu ọrọ tiẹ, Ayu sọ fun Obasanjo pe ''ti o ba fi PDP silẹ, ẹjẹ PDP ko le kuro lara rẹ.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Ẹgbẹ oṣelu PDP yoo si maa tọ ọ wa fun amọran gẹgẹ bi baba loore koore.''

Obasanjo jẹ aarẹ alagbada orilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP laarin ọdun 1999 si ọdun 2007.

Àkọlé fídíò, Eba