Police missing arms and ammunition: Ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà, níbo làwọn ìbọn 178, 549 wọlẹ̀ sí, àwọn aṣòfin àpapọ̀ ń béèrè

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force
Ile igbmọ aṣojuṣofin Naijiria ti bẹrẹ si ni tan ina wadii bi awọn ibọn ati ọta to le ni ẹgbẹrun mejidinlaadọsan, ṣe sọnu mọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lọwọ.
Ile aṣojuṣofin Naijiria bẹrẹ iwadi naa lẹyin ti wọn fẹnu ko lori aba kan ti Họnọrebu Toby Okechukwu, igbakeji olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere nile aṣofin naa gbe ka iwaju ile.
Ninu iwe abajade iwadi ọfiisi oluyẹweowo wo agba ni Nigeria, iyẹn office of the Auditor General of the Federation ti ọdun 2019 ni ọrọ yii ti lu sita
Won ni pe ibọn ati ọta ẹgbẹrun mejidinlaadọsan ati ọtalerinwo o din ẹyọkan, 178,459 to jẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lo ti poora.
Awọn Họnọrebu naa tun ranṣẹ pe ọga agba patapata nileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lati tete mu awọn to wa nidi bi ibi ikonkan ija ọlọpaa si ṣe n yoro.
Kini o bi ọrọ yii sita?
Gẹgẹ bi Họnọrebu Okechukwu ṣe sọ nigba to n gbe aba rẹ kalẹ niwaju ile.
O ni pe ayẹwo iwe ibọn awọn ọlọpaa, ayẹwo iye ibọn ati ọta ti wọn lo loṣooṣu ni ibudo iko-nkan- ija-ọlọpaa pamọ si lo fihan pe iye ibọn lọpaa to nu titi di oṣu keijla, ọdun 2018 jẹ mejidinlaadọsan ati ọtalerinwo o din ẹyọkan, 178,459.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force
Awọn ariwisi wo lo sọ?
Honorebu naa ṣalaye siwaju sii peẹgbẹrun mejidinlaadọrun o le mejidinlọgọrin awọn ibọn to sọnu ni wọn jẹ ẹya ibọn AK-47 rifles, ẹgbẹrun mẹta ati ẹẹdẹgbẹrun o le meje ninu wọn lo jẹ ẹda awn ibọn atamatase miran ati ibọn ilewọ.
Bakan naa lo ni awọn adari ileeṣẹ ọlọpaa ko lee ṣe afihan iye ibọn ọlọpaa to ti bajẹ ti ko si ṣe e tun ṣe mọ.
Bakan naa lo ni lawọn asiko ti wọn gbe yẹwo yii, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Adamawa, pẹlu ẹka ọlọpaa kogberegbe Mobile Police ni ibudo MOPOL 46, 56, 64 ati 68 ni ko tilẹ jihin bi wọn ṣe lo ibọn si ati iye ibọn ati ọta to wa ni ikawọ wọn.
Aṣofin naa fi kun un ko ibanujẹ nla lo jẹ pe ko tilẹ si bi wọn ṣe le e diyele awọn ibọn ati ọta to sọnu naa nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa ko lee ṣe agbekalẹ awọn iwe akọsilẹ gbogbo to yẹ.
















