Ta ni Rasheed Balogun, alákòso ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars to dolóògbé?

Rasheed Balogun

Oríṣun àwòrán, @Rasheed Balogun

Lale ana ni Balogun Rasheed jade laye!

Rasheed Balogun to jẹ alakoso ẹgbẹ agbabọọlu 'Shooting Stars' yii lo re ibi agba n re ni ogunjọ ọsu kinni, ọdun 2022 yii.

Lati igba ti o ti doloogbe ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n beere nipa oloogbe naa.

Won kede iku rẹ lẹyin aisan ranpẹ ko to o doloogbe nile iwosan ni Ibadan

Loni, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kinni, ọdun 2022 ni eto isinku rẹ a waye

Shooting Stars

Oríṣun àwòrán, Others

Ta ni Rasheed Balogun?

Rasheed Balogun jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta.

O gba igbega si Nigeria Professional Football League lọdun karun un lẹyin ti wọn kuro ni Nigeria National League.

Rasheed Balogun

Lọdun 2014 ni ijọba ipinlẹ Oyo yan Rasheed Balogun gẹgẹ bii alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars.

Bakan naa ni Balogun ṣiṣẹ pẹlu ikọ agbabọọlu Dolphins ni Port Harcourt ni ipinle Rivers.

Rasheed Balogun

Rasheed sise bi alakoso Dolphin ki o to lọ si ọdọ awọn ikọ Sunshine Stars nibi to ti jẹ alakoso ikọ naa.

O ṣe igbeyawo, o si bimọ.

Rasheed Balogun

Iroyin naa ni o saisan fun igba die ki ọlọjọ to de.

Oni ni wọn sín Oloogbe Rasheed Balogun ni ile rẹ to wa ni Mowe ni ipinle Ogun.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Rasheed Balogun tó jẹ́ alákóso ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars ní Ibadan ti jáde láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajo yajo ni pe alakoso ikọ agbabọọlu Shooting Stars to fi Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni Guusu Iwo Oorun Naijiria ṣe ibujoko ti jade laye.

Rasheed Balogun

Ogbeni Rasheed Balogun ni wọn ni pe o ti rẹ ẹ diẹ tẹlẹ ni ọna ọfun rẹ.

Okan ninu awọn akọnimọọgba ẹgbẹ naa lo fidi ẹ mulẹ pe iku ti mu Rasheed Balogun lọ.

Iroyin naa ni pe o jade laye ni ogunjọ oṣu yii.

Àkọlé fídíò, Kaun

Awọn ẹgbẹ Ibadan Football Association naa ti fidiẹ mulẹ pe wọn padanu akinkanju kan.

Won ti sun idije bọọlu to yẹ ko waye loni siwaju.