Abdulsalami Abubakar warning: Abdusalami ṣèkìlọ̀ fún Buhari lórí yíyọ ìkúnpá orí epo rọ̀bì

Oríṣun àwòrán, @Abdulsalam Abubakar
Olori orilẹ-ede Naijiria nigba kan ri, Abdusalami Abubakar ti sọrọ soke lori afikun owo bentiroolu.
Saaju ni iroyin ti gbode kan pe ijọba Naijiria n gbero lati fi kun owo epo béntiroolu ni Naijiria ni eyi ti awọn eeyan si ti ni ero ọtọọtọ le lori.
Abdulsalami sọ̀rọ̀ yìí níbi àpérò ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Daily Trust tó wáyé ní ìlú Abuja níbi tó ti ní ìpèníjà tó ń kojú àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pọ̀ ju kí ìjọba tún yọ ìkúnpá orí epo.
- Wo bí ọlọ́pàá ṣe rí òkú ọmọ ọdún márùn-ún tí wọ́n ní olùkọ́ rẹ̀ jígbé
- Níbo ni ìbọn 178, 549 wọlẹ̀ sí níléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà?
- Rasheed Balogun tó jẹ́ alákóso ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars ní Ibadan ti jáde láyé
- Owó ẹjọ́ Makinde dá wàhálà sílẹ̀ láàrín àwọn adárí káńsù lásíkò Ajimobi l'Oyo
- Mínísítà fí ìkìlọ síta lẹyìn tí òjò àrọ̀rọ̀dá àti àrá sán pa èèyàn 82
- Oníbárà tí a bá mú lẹ́sẹ̀ títì yóò sùn ẹ̀wọ̀n- ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara
Ẹ ó rántí pé ìjọba lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kéde láti yọ ìkúnpá orí epo pẹtiró nínú oṣù kẹfà ọdún 2022.
Èyí sì ti ń fa kí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀, tó fi mọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NLC) ti ń sọ pé ìgbésẹ̀ náà kò dáa tó látàrí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí ń kojú lásìkò yìí.
Abdulsalami fi kun pé ó lé ní ọgọ́rin mílíọ̀nù ènìyàn ló wà nínú iṣẹ́ àti òṣì àti pé àìní iṣẹ́ lọ́wọ́ ń peléke si.
Bákan náà ló ní ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ń fi ojoojúmọ́ pọ̀ si pàápàá pẹ̀lú bí COVID-19 àti àwọn agbébọn ń da orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàmú.
Ógagun naa ní gbogbo èyí ń kó ipa tí kò dára sí iye oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà kò ní le rà á.
Ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú gbogbo èyí tí owó epo bá tún lé kún, yóò tún jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn tún lé kún nínú òṣì àti ìṣẹ́















