South Africa severe weather kills: Mínísítà fí ìkìlọ síta lẹyìn tí òjò àrọ̀rọ̀dá àti àrá sán pa èèyàn 82

South Africa

Oríṣun àwòrán, @Govtchat.rog. South African Govt

Wo ìlànà tí Mínísítà ni orilẹ-ede South Africa gbé kalẹ̀ lẹyìn tí òjò àrọ̀rọ̀dá àti àrá sán pa èèyàn 82

Eeyan mejilelọgọrin ti padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ omiyale ati ara sisan to ba ojo arọrọda wa lorile-ede South Africa.

Minisita feto ajumọsepọ ijọba ati ọrọ ibilẹ lorileede naa, Nkosazana Dlamini Zuma lo fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n parọwa si araalu lati sọra se lasiko ti wọn n koju iyipada oju ọjọ yi.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Minisita naa salaye pe ''ojo to n rọ larọrọda yi n lapa lara awọn ileto wa lọna ti ko da nitori eeyan mejilelọgọrin lo ti padanu ẹmi wọn nipasẹ pe omi gbe wọn lọ tabi ti ara san pa wọn''

O ni isẹlẹ yi ti wa jẹ ko di dandan ki ijọba ati araalu wa ọna lati dẹkun ijamba yi.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Oro Isaaju Minista:

Nkosazana Dlamini Zuma tẹsiwaju pe ''ko si ẹni to ko nifẹ si ojo nitori a maa se iranwọ nipa kikoju ipenija aisi omi lawọn apa ibi kan lorileede wa.

O se ni laanu pe arọrọda ojo to waye ti se akoba lọpọ ibi to si se idiwọ fun lilọ ati bibọ awọn eeyan''.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Lọna ati sọ ẹmi araalu lọwọ ijamba yi, Minisita wa kede awọn ilana wọn yi faraalu lati tẹle:

- Tẹti si ikilọ pataki lori redio,oju opo ayelujara ati ẹrọ amohunmaworan

- Nibi to ba ri pe o rọrun, ma se jade nile lasiko ti ojo arọrọda baa n rọ

- Yago fawọn agbegbe ti omiyale ti wọ pọ

-Yago fun wiwẹ ninu tabi sisọda kọja odo to ba ya lasiko ojo

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

- Ma se sọda lori afara tabi oju ọna ti ojo ba ti kun sori rẹ

- Awọn to ba wa loju agbara gbọdọ sipo kuro lọ si ibi ti omi ko ti ni se akoba fun wọn

Àkọlé fídíò, Eba

-Yago fawọn aaye tiomi ba ti yale.Koda nibi ti omi ko ti pọ ewu mii le wa nibẹ

- Ma se rin loju ọna ti omi ba ti wọ titi lọ,yago fun ibi ti ilẹ ba ti ya, igi tabi opo ina ti o ba ti wo lulẹ

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

- Daabo bo awọn ọmọ ko ri pe wọn ko ja si odo to ba ti kun fa ya

Lakotan, o rọ awọn obi ati alagbatọ lati seto ilana idaabo ninu ile wọn ati ni ile ẹkọ.