Ex-ALGON N1billion: Owó ẹjọ́ Makinde dá wàhálà sílẹ̀ láàrín àwọn adárí káńsù lásíkò Ajimobi l'Oyo

Oríṣun àwòrán, other
Awọn agba bọ wọn ni owo nii boju ọrọ jẹ.
Owo ọhun lo dabi ẹni n da rugudu silẹ bayii laarin awọn alaga kansu, awọn igbakeji wọn atawọn kasilọ lapa kan pẹlu awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super'
Koda, ko yọ awọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) lapa keji ni ipinlẹ Ọyọ.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọdun 2021 ni ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria gbe idajọ kalẹ pe ki ijọba ipinlẹ Ọyọ san gbogbo owo oṣu atawọn ajẹmọnu to tọ sawọn alaga kansu.
Ati ti awọn igbakeji wọn atawọn kansilọ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọyọ fun iye oṣu ti saa iṣejọba wọn yẹ ko jẹ.
- Ọmọ ọdún 14 gún ara rẹ̀ pa lẹ́yìn tí okùnrin ẹni ọdún 35 fi ipá balòpọ̀
- Wo bí àbẹ̀wò ọjọ́ méjì tí Aarẹ Buhari ṣe sí Kaduna yóò ṣe lọ
- A óò yọ àwọn ọmọ Naijiria kúrò nínú ìṣẹ́, òṣì, ìṣòró ètò aàbò àti àìmọ̀kan- Tinubu
- Ọlọ́pàá Oyo bẹ̀rẹ̀ kán lu ìgbó láti wá àwọn ajínigbé lópópónà Lagos-Ibadan Expressway
- Njẹ́ ọ̀rọ̀ ipò gómínà Osun ní 2022 kò fẹ́ ẹ̀ da ẹbí Adeleke rú báyìí?
Ni oṣu kejila ọdun 2021 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ paṣẹ ki wọn san biliọnu kan Naira ninu owo naa fun awọn adari kansu naa ti wọn dibo yan labẹ iṣejọba gomina ana nipinlẹ Ọyọ Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.
Owo naa ti ijọba ti san lo wa n da wahala silẹ bayii lagbo awọn adari iṣejọba ibilẹ tẹlẹ naa ti wọn pe orukọ wọn ni EX-ALGON.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ ilana ipinwo ti wọn gbe kalẹ, ninu eyi ti awọn alaga ti gba miliọnu meji abọ naira (N2.5 milion).
Ti won si fun awọn igbakeji alaga ni miliọnu kan abọ naira (N1.5million), ati awọn olori ile aṣofin kansu ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N1.3million).

Oríṣun àwòrán, @Oyo state affairs
Leyin naa ni won fun awọn kansilọ ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba (N1.2milion).
Ti wọn si tun pin aadọrun ẹgbẹrun (N90,000) fun ọkọọkan awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff).

Oríṣun àwòrán, Inside Oyo
Ki ni iha t'awọn adari ijọba ibilẹ ti wọn dibo yankọ si ọrọ naa?
Ninu ọrọ to sọ fun BBC News Yoruba, alaga ẹgbẹ awọn alaga kansu ti gomina Makinde le kuro nipo naa, Ọmọọba Abass Alẹṣinlọyẹ ṣalaye pe, ko si ọrọ pinpin owo laarin awọn atawọn awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super'.
Koda, O ni ko kan awọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) nitori pe gẹgẹ bi idajọ ile ẹjọ giga julọ ni Naijiria ṣe gbe e kalẹ.
- Àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá márùn ún tó gbégbá àpótí òṣèlú ní Nàìjíríà
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
- Afárá Marina yóò ṣì wà ní títì pa fún ìgbà díẹ̀ fún àtúnṣe
- Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá ba akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìyàwó, ikú dé!
- Hajiya Binta Balarabe Kubaus rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he lẹ́yìn tó lu jìbìtì ₦5.5m
Ọmọọba Alẹsinlọyẹ ni awọn alaga, igbakeji wọn ati kansilọ kansu naa kan woye ninu aanu wọn lati fi lara owo ti wọn fun wọn tọrẹ fun awọn awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) naa ni.
O ni kii ṣe pe wọn lẹtọ sii.
O ṣalaye siwaju sii pe idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ ni pe ki ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ san owo fun awọn adari ti wọn dibo yan ni kansu; awọn adari ti wọn si dibo yan ni Alaga, igbakeji rẹatawọn kansilọ.
Ọmọọba Alẹsinlọyẹ ni pe: "Wọn fun wọn lowo ni, kii ṣe owo oṣu wọn.
Bi ẹ ba fẹ mọ, ẹwo idajọ ileẹjọ naa.
Ẹ wo apo iṣuna agbẹjọro to gbọ ẹjọ naa, aṣuwọn wọn ni wọn fi n san owo naa.
Idajọ o ko wọn mọ awọn ti yoo gba owo.
Wọn o si ninu idajọ ile ẹjọ. Wọn kan n pariwo ni."
Ọmọọba Alẹsinlọyẹ fi kun un pe ilana owo oṣu ti kaluku awọn adari ti wọn dibo yan naa wa lasiko ti wọn wa ni iṣejọba ni wọn fi pin owo naa kan wọn.
O ni bi awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) naa ba si wo o pe awọn lẹtọ sii labẹ idajọ naa, a jẹ pe awọn ati gomina ipinlẹ Ọyọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ẹlẹjọ.
Ki lawọn Super, akọwe ijọba ibilẹ ti Makinde yọ nipo naa n sọ bayii?
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) ti n gbe igbesẹ lati gba ile ẹjọ lọ lati tako ohun ti wọn pe ni iwa wọbia awọn adari ijọba ibilẹ ti wọn dibo yan naa.
Awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) ti fi atẹjade kan sita.
Won ni iwa ọbayejẹ gba lawọn adari ijọba ibilẹ naa hu si awọn nitoripe niwoye awọn, ko si bi wọn ṣe le to o, pataki ni wọn ninu eto iṣejọba ibilẹ nigba naa.
Ipinya wa laarin awon ti oro kan lori iwa 'alaimoore'ti wọn n hu bayii:
Amọṣa, kii ṣe gbogbo awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) lo wa lori igbesẹ yii.
Awọn kan ya kuro lẹyin ipe yii ti wọn si n kan saara si awọn adari ijọba ibilẹ ti wọn dibo yan naa pe ore ni wọn ṣe wọn.
Awon wo lo ti ya kuro ninu ipe ẹjọ naa?
Arakunrin Taiwo Bamigbade to figba kan ri jẹ alamojuto ẹka iṣẹ ode nijọba ibilẹ Inu kan LCDA ti olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa fikalẹ si ilu Ajia ṣalaye fun BBC News Yoruba pe aimoore gba a lo n da awọn akẹgbẹ oun laamu nitori pe wọn ko mọ ipo wọn ni.
"Alaimoore ẹda ko ni salai ma moore.
Ẹ dakun, wọn ni wọn bun ọ lowo, o nkaa wo, ṣe waa sọ pe owo naa o pe ni?
Iwọnba perete lawọn to lọ si ile ẹjọ ninu wọn.
Bi wọn ba le lọ si kọọtu wọn a mu ofo bọ ni"
Nibo ni won ti ri owo?
Taiwo ni fi kun un pe alaga ẹgbẹ awọn alaga kansu ti wọn dibo yan labẹ iṣejọba gomina ana, Sẹnetọ Ajimọbi, iyẹn Ọmọọba Abass Alẹshinlọyẹ lo rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati ya owo diẹ sọtọ.
O ni ki wọn yọ ọ ninu owo to ba kan olukuluku wọn.
Ati pe eyi wa lati le e fun awọn awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) naa.
- Ilé ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Abia pàṣẹ fún DSS láti san bílíọnù kan Naira fún Nnamdi Kanu
- Ki ló fa awuyewuye lórí ìrẹsì gogoro tí Aàrẹ Buhari ṣé ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ lAbuja?
- Wo bí ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n jígbé ni Ibadan sí Eko ṣe gba òmìnira lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá
- Lóòtọ́ ni àrùn Lassa ti wọ ìpìnlẹ́ Oyo, àmọ́ ẹ má mikàn- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- Ọlọ́run Tinubu kìí ṣé Ọlọ́run témi torínáà mi o ní gbè lẹyìn rẹ̀ ní 2023- Ojudu
- Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Abia àti Imo wọ àṣo àsíá Biafra bí o ṣe jáde lórí ayélujára?
Ki ni igbesẹ ti wọn fẹ gbe bayii?
Ni bi a ṣe n ko iroyin yii jọ, ohun ti a gbọ ni pe, awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) naa ti n wa ọna lati da owo jọ fun ipẹjọ lori ọrọ naa.
Bakan naa ni a si tun n gbọ pe, ọpọ awọn adari ijọba ibilẹ ti wọn dibo yan naa, paapaa julọ awọn kansilọ ti n yi ọrọ pada.
Awon to gba tẹlẹ pe ki wọn yọ lara owo to kan wọn fun awọn awọn akọwe ijọba ibilẹ, awọn alamojuto ẹka iṣejọba nijọba ibilẹ ti ọpọ mọ si 'Super' atawọn akọwe ijọba ibilẹ ati olori oṣiṣẹ lọfiisi alaga ijọba ibilẹ (Chief of staff) naa ni wọn ti fariga bayii pe ko ni le e ri bẹẹ mọ nitori iwa ti wọn hu naa.






















