Kwara barns beggers: Oníbárà tí a bá mú lẹ́sẹ̀ títì yóò sùn ẹ̀wọ̀n- ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara

Kwara

Oríṣun àwòrán, @Kwara State Govt

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn tí tọwọ́ bọ àdéhùn pẹ̀lú àwọn Hausa tó ń gbé ní ìlú Ìlọrin pé àwọn oníbárà kò gbọdọ̀ máa tò sí àwọn ojú ọ̀nà mọ́ láàárín ìgboro.

Kọmíṣọ́nnà fún ìdàgbàsókè àwùjọ Ìpínlẹ̀ Kwara, Abosede Aremu ló ṣíṣọ lójú eégún ọ̀rọ̀ ọ̀hún fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Ìlọrin ní Ọjọ́ bọ̀.

Abosede Aremu ṣàlàyé pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà látàrí à ti fi òpin sí àwọn ìwà kòtọ́ tí àwọn oníbárà náà má ń wù ní àwọn òpópónà káàkiri ìlú Ilorin.

Kọmíṣọ́nnà náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn àti àwọn adarí àwọn Hausa tí fẹnukò, tí àgbọ́yé sì ti wà láàárín wọn.

Bákan náà ló rán àwọn ará ìlú létí pé ìjìyà wà fún títọrọ bárà ní àwọn òpópónà gẹ́gẹ́ bí òfin tó de bárà gbígbà lẹ́sẹ̀ títì Ìpínlẹ̀ Kwara ọdún 2006 ṣe là á kalẹ̀.

Àkọlé fídíò, Kaun

Awon Aṣoju ni agọ hausa wo lo tọwọ bọ iwe adehun naa?

Àwọn aṣojú Hausa tó wà níbi títọwọ́ bọ àdéhùn náà ni Surajudeen Hussain, Rufai Sanni àti Mohammed Lawal tí wọ́n sì sọ àrídájú àtìlẹyìn wọn fún ìjọba pé àwọn oníbárà náà yóò kúrò lẹ́sẹ̀ títì.

Ẹ ó rántí pé ọ̀pọ̀ àwọn oníbárà ni wọ́n ya wọ Ìpínlẹ̀ Kwara láti ẹkùn Árìwá orílẹ̀ èdè yìí.