Ibadan Robbery: Ènìyàn mẹ́rin kú lásìkò tí wọ́n ń lé olè tó ja àwọn oní PoS lólè n'Ibadan

PoS

Àwọn ọlọ́kadà àti ará àdúgbò Omi Ado mẹ́rin ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo, ti pàdánù ẹ̀mí wọn, nígbà tí wọ́n ń lé àwọn afurasí olè kan tó wá ṣọṣẹ́ ní agbègbè náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà náà yabo agbègbè Ladeowo ní Omi Ado lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì ní nǹkan bí ago méje ìrọ̀lẹ́, tí wọ́n sì ń gba owó lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe POS.

Bí i ṣọ́ọ̀bù márùn-ún ni wọ́n ti ṣọsẹ́ kí àwọn ará ìlú tó fi igbe ta léyìí tó mú kí àwọn olè náà fi ẹsẹ́ fẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Óṣojúmi kòró tó bá àwọn àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní kété tí àwọn olè náà fẹsẹ̀ fẹ ni àwọn ọlọ́kadà àdúgbò náà àti àwọn ará ìlú náà bá gbé ọ̀kadà láti fi lé àwọn olè yìí.

Ṣùgbọ́n ní kété tí àwọn olè náà mọ̀ wí pé àwọn ènìyàn náà ń lé àwọn ni wọ̀n dàbọn bolẹ̀ tí ìbọn sì ba ènìyàn mẹ́rin nínú àwọn ènìyàn náà.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Bákan náà ló ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti pe àwọn ọlọ́pàá lálẹ́ ọjọ́ náà ló já sí pàbó bí wọn kò ṣe gbé fóònù títí tí àwọn olè náà fi sá lọ.

Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà - iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso ní àwọn ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà tí àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí le lórí.

Osifeso ní kété tí àwọn bá ti ni ohun tuntun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn yóò fi léde.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit