Aisha Buhari #PrayForNigeria: Aisha Buhari pè fún àdúrà, wo èsì tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fọ̀ padà lórí ìpè yìí

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aisha Buhari
Abẹla ti ina rẹ ko mọlẹ daada pẹlu hashtag ẹ gba adura fun Naijiria ni iyawo aarẹ Aisha Buhari tun fi da awuyewuye silẹ lati Dubai to wa.
Lọjọ Aiku ibẹrẹ ọsẹ mii ni iyawo aarẹ Aisha Buhari ti awọn eeyan ko ti gburo to ọjọ mẹta fi ọrọ yi soju opo rẹ.
Ni oju opo Facebook rẹ ti a ti ka awọn esi ti ọrọ yi muwa, niṣe ni ero ṣe ọtọọtọ laarin awọn ọmọ Naijiria.
Bawọn kan ṣe n beere pe ki lo ṣe Naijiria to fi ni kawọn maa gbadura lawọn mi n sọ pe ki iyawo aarẹ lewaju adura ṣise fun Naijiria.
- Èmi kò sí nílé, ọkọ́ mi ló leè sọ bóyá lóòtọ́ọ́ ló fẹ́ gbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha fèsì
- Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára
- Ọmọ Nàìjíríà, ẹ forijìn mí! Aisha Buhari tọrọ ìdáríjì lórí fídìo tó jáde
- Ta ni yóò borí láàrin Aisha Buhari àti ọkọ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ‘First Lady’?
Nigba taa fi ka iye ọrọ to ti tẹle aworan Aisha Buhari, abẹla ati ọrọ kewu to fi sọ pe ''Allah lo to ni ẹni a gbọkan le fun iranwọ yi'' ilẹ ti kun fọfọ.
Lapapọ o ti le ni gbẹrun kan iriwisi tawọn eeyan ti sọ lori ọrọ yi tawọn eeyan si ti pin ọrọ naa ni igba igba le diẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aisha Buhari
Odabi ni pe ọrọ ipe fun adura yi ba awọn ọmọ Naijiria lasiko ti ara n kan wọn. Ọpọ ko ri si ipe iyawo aarẹ yi ti wọn si ni pe awọn fura si pe nkankan n ṣẹlẹ lo mu ki o ni kawọn maa gbadura.
Ni paapa awọn kan sọ pe iyawo aarẹ n wa nkankan ti ko ti rii lo mu ki o sọ pe kawọn maa gbadura.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aisha Buhari
O ti to ọjọ mẹta kan ti iyawo aarẹ Aisha Buhari ti kuro lorileede Naijiria lọ si orileeede Dubai.
Lẹnu igba to wa nibẹ yi, awọn eeyan ko gburo rẹ ju pe awọn iyawo Gomina Naijiria kan lọ ṣabẹwo si lati fi ki ku oriire ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Koda wọn tun gbe akara oyinbo lọwọ ti fọnran fidio abẹwo yi si gbalẹ kaakiri oju opo ayelujara.
Aisha Buhari kii ṣe ẹni to maa n dakẹ lori ọrọ Naijiria ti a si maa dasi ọrọ ilu loore koore.
Koda nibi didasi ọrọ ilu yi, o ti tako ijọba ọkọ rẹ ri to si ti sọ pe awọn kan ti gba ijọba mọ ọkọ oun lọwọ.
Lọpọ igba to ba mẹnu ba iṣẹlẹ ni Naijiria awọn onwoye s pe kii ṣe nitori ifẹ ilu bi kii ṣe pe o ninkankan to fẹ gba ti ko tẹ ẹ lọwọ.
Lara didasi ọrọ lẹnu ọjọ mẹta yi la ti la ti ri pe o fi ọrọ si oju opo rẹ nipa ipade gbogboogbo ẹgbẹ APC to pada waye lana.
Ipade tipari lana ti wọn si ti yan awọn adari ẹgbẹ APC tuntun.Boya awọn to wọle jẹ ẹni ti iyawo aarẹ fẹ tabi ko ri bẹ, a kole sọ.
Eyi to kan han si wa ni pe ọrọ sunukun lo sọ nipa adura yi ti awọn ọmọ Naijiria naa si ti n fi oju sunukun fi ba wo.












